Faith Adebọla
“Mo ti le lẹni aadọrin (70) ọdun bayii, ṣugbọn ka sododo ọrọ, mi o ti i figba kan ri i ki orileede yii bajẹ to bo ṣe ri lasiko yii ri, Naijiria o ti i figba kan bajẹ to bii eyi ri, ti iṣọkan sọnu patapata, ko si aabo rara, eto ọrọ-aje si polukurumuṣu.”
Nibi apero apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP to waye niluu Abuja, lọjọ Abamẹta, Satide, ọgbọnjọ, oṣu yii, ni Abubakar Atiku ti sọrọ yii.
Atiku, Igbakeji aarẹ orileede wa lasiko iṣejọba Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ sọrọ nibi ayẹyẹ naa pe anfaani kan ṣi ṣẹku fun wa lati so orileede yii pọ niṣọkan, ka si bẹrẹ si i ṣatunto gbogbo nnkan to ti daru, o ni eto idibo ọdun 2023 ni anfaani naa.
Bi wọn ṣe kede ninu ẹrọ abugbamu pe ẹni ti ọrọ kan ni Atiku, niṣe lawọn ololufẹ rẹ, atawọn oṣere rọ jade, gbogbo wọn ni wọn wọ aṣọ ipolongo Atiku fun ipo Aarẹ lọdun 2023, ti wọn si bẹrẹ si i kọrin, wọn n jo, wọn si n fi idunnu wọn han. Ariwo naa pọ debii pe niṣe ni Atiku bẹrẹ si i parọwa fun wọn pe ki wọn foun laaye diẹ lati sọrọ, gbogbo gbọngan apero naa lo rọ kẹkẹ lasiko ọhun.
Atiku ni: “A ni lati bẹrẹ si i to gbogbo ohun to ti bajẹ wọnyi. Iyan orileede yii maa di atungun, ọbẹ rẹ si maa di atunse.
A ṣi lanfaani lati so orileede yii pọ niṣọkan, ko le goke agba bo ṣe tọ, ki ala rere awọn baba nla wa to fipilẹ rẹ lelẹ lọdun pipẹ sẹyin le wa si imuṣẹ, a lanfaani lati fi ẹsẹ orileede yii le ọna ti yoo fi wa nipo ajitannawo laarin awọn orileede agbaye to ku. Ẹ jẹ ka doola ẹmi orileede yii, ka doola ẹmi ara wa, ka doola ẹmi ẹgbẹ oṣelu wa.
Ẹ jẹ ka lọọ gbaradi de ọdun 2023, a gbọdọ lo anfaani yẹn lọdun 2023.”
Bakan naa ni ọkunrin to ti dupo aarẹ lọpọ igba sẹyin yii sọ pe inu oun dun gan-an si ohun to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party lasiko yii, o ni ẹgbẹ naa ti fihan pe lai ka awọn ipenija to koju si, ẹgbẹ oṣelu to to gbangba a sun l’ọyẹ ni.
O fawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ọhun atawọn ololufẹ rẹ lọkan balẹ pe didun lọsan maa so fẹgbẹ PDP ati Naijiria laipẹ, o ni ki wọn ṣe suuru diẹ si i, ki wọn si fọwọ sowọ pọ.