Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lẹyin ti wọn ti wa si Owode Yewa lẹẹmẹta, ti wọn si ti fi ọgbọn buruku gba ọkada lọwọ eeyan mẹta lasiko ọtọọtọ, ọwọ palaba Chidi Umeh, ẹni ogoji ọdun, ati Obinna Onyebuchi, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ti wọn n ti ipinlẹ Anambra, nilẹ Ibo, waa ja ọkada gba nipinlẹ Ogun ti segi.
Ojọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ yii, ni awọn ọlọpaa teṣan Owode-Ẹgbado, gba ipe kan pe awọn ọkunrin meji kan ti fẹẹ gbe ọkada ọlọkada kan lọ laduugbo Alaanu, l’Owode-Yewa, lẹyin ti wọn ti fun ọlọkada naa ni nnkan mu, tiyẹn si ti sun kalẹ bii oku.
Nigba ti DPO teṣan naa, Ọlabisi Elebute, debẹ ti wọn fọwọ ofin mu awọn ọmọ Ibo yii ni wọn sọ orukọ wọn ati ibi ti wọn ti wa.
Chidi ṣalaye pe paati ọkada loun n ta ni Nnewi, lati ibẹ loun ti maa n wa si Owode Yewa lati gba ọkada ọlọkada, oun yoo si lọọ tu u ta niluu oun.
Lori ọgbọn to n lo fawọn ọlọkada naa, ọkunrin yii sọ pe oun maa n ṣe bii ẹni ṣe wọn loore ni, nitori oun maa n fi nnkan mimu ti ko ni i jẹ ko rẹ wọn (Energy drink) lọ wọn, bẹẹ oun yoo ti foogun oorun sinu nnkan mimu naa, eyi to ba fi le gba a lọwọ oun ninu awọn ọlọkada naa, to si mu un, yoo sun lọ fọnfọn ni, bẹẹ loun yoo ṣe gbe ọkada rẹ lọ tefetefe, toun yoo lọọ tu u ta nipinlẹ Anambra.
Koda, DSP Abimbọla Oyeyẹmi sọ pe ọlọkada ti wọn gba maṣinni rẹ ṣikẹrin ti aṣiri wọn fi tu yii ko ti i ji lasiko ti awọn mu Chidi ati Obinna, niṣe lo ṣi n sun fọnfọn lọsibitu ti wọn gbe e lọ latari nnkan mimu ti awọn ọmọ Ibo yii fun un mu.
Ni ti Obinna ti wọn jọ mu wọn, oun sọ pe igba akọkọ ree toun yoo tẹle Chidi wa s’Owode waa jale, ṣugbọn apapọ ọkada ti wọn ti fi atẹnujẹ gba lọwọ awọn ọlọkada jẹ mẹrin.
Eyi ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fi kilọ fawọn ọlọkada, pe ki wọn ma gba nnkan jẹ, tabi mu, lọwọ ẹni ti wọn ko mọ ri to kan fẹẹ gun ọkada wọn lasan, ko ma di pe atẹnujẹ yoo ko ba wọn, ki anfaani ma si le fi wa fawọn to n lo ọgbọn buruku naa lati jale.