Ọlọpaa sa kuro ni teṣan l’Akurẹ, nitori awọn ọlọkada to fẹẹ gbẹsan iku ẹlẹgbẹ wọn ti wọn pa

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọpọ awọn ọlọpaa A Difisan to wa lagbegbe Oke-Ẹda, l’Akurẹ, ni wọn n fo fẹnsi  jade, ti awọn mi-in si n bọ aṣọ iṣẹ wọn sọnu lasiko tawọn ọlọkada n fẹhonu han ni teṣan ọhun latari ọkan ninu wọn ti wọn yinbọn pa.

Ijamba ọkọ kan lo kọkọ waye laduugbo Arakalẹ ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ aarọ ọjọ naa, ninu eyi ti ọlọkada kan ati ero to gbe sẹyin ku si.

Awakọ bọọsi kan lo ṣeesi kọ lu ọlọkada ohun ati ero to gbe sẹyin, ti awọn mejeeji si ku loju-ẹsẹ, ibi to ti n gbiyanju ati sa kuro lagbegbe naa nitori ibẹru lo tun ti kọ lu ọlọkada mi-in to n bọ niwaju.

Iṣẹlẹ yii lo mu kawọn eeyan pejọ si ojuko ibi ti ijamba ọkọ naa ti waye, leyii to fa sún-kẹrẹ fa-kẹrẹ awọn ọkọ lagbegbe ọhun fun ọpọ wakati.

Ọlọpaa to n sọ ileepo kan to wa nitosi ibi iṣẹlẹ ọhun ni wọn lo bẹrẹ si i parọwa sawọn ọlọkada pe ki wọn waa gbe ọkada wọn kuro niwaju ibi ti oun n mojuto, ṣugbọn ti wọn kọ eti ikun si arọwa rẹ.

Nigba to su ọlọpaa yii lo deedee yinbọn soke lojiji lati fi tu awọn oluworan wọnyi ka, dipo tawọn ọlọkada iba si fi gbọ ikilọ ki wọn tete gbe ọkada wọn kuro nileepo naa, ṣe ni diẹ ninu wọn mura ija, ti wọn si fẹẹ ja ibọn Ak47 ọwọ rẹ gba.

 

Ibi ti agbofinro ọhun si ti n yinbọn soke kikankikan lati gba ara rẹ silẹ ni ìbọn ti ba ọkan ninu awọn ọlọkada naa, to si ku loju-ẹsẹ.

Ẹru ibọn ti ọlọpaa yii n yin soke leralera ko jẹ kawọn tinu n bi le sun mọ ọn, ọpọ wọn la ri ti wọn n ju okuta, nigba tawọn mi-in n ju igi lu u.

Wọn ṣe e leṣe diẹ ko too raaye jajabọ, to si sa lọ si tesan A Difisan ti ko fi bẹẹ jinna sibi iṣẹlẹ naa.

Kiakia lawọn ọlọkada ti bẹrẹ ifẹhonu han, wọn di gbogbo oju ọna to ṣe koko l’Akurẹ pa bẹẹ ni iná n sọ lau loju popo.

Lẹyin eyi ni wọn mori le A Difisan, wọn si fi dandan le e fun ọga ọlọpaa tesan ọhun ko tete fa ọlọpaa naa le wọn lọwọ ki wọn le gbẹsan ọkan ninu wọn to ran lọrun ọsan gangan.

Ohun tawọn ọlọpaa tesan ọhun ri ree ti olukuluku wọn fi ki ere mọlẹ ti wọn si n gba ibikibi ti wọn ba ti rí sa lọ.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmi Ọdunlami, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu ọrọ to b’ALAROYE sọ lori ago.

O ni ọlọpaa ọhun ṣi wa nileewosan kan ta a forukọ bo laṣiiri, nibi to ti n gba itọju latari lilu ti wọn lu u.

Leave a Reply