Stephen Ajagbe, Ilọrin
Bawọn akẹkọọ ileewe girama ṣe n gbaradi fun idanwo aṣekagba, WAEC, to maa bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to n bọ, ijọba ipinlẹ Kwara ti ṣekilọ fawọn ọga ileewe atawọn obi lati ma lọwọ ninu ṣiṣe eru idanwo.
Atẹjade kan ti Akọwe iroyin nileeṣẹ ijọba to n mojuto eto ẹkọ, Yusuf Ali-Agan, gbe sita lọjọ Ẹti, Furaidee, lorukọ Kọmiṣanna Hajia Fatimah Ahmed, ni ẹni tọwọ ba tẹ to ṣe makaruru tabi magomago idanwo yoo fimu kata ofin.
O ni ibi ipade to waye laarin kọmiṣanna ọhun pẹlu agbarijọpọ awọn ọga ileewe, ANCOPSS, awọn oludasilẹ ileewe aladaani atawọn adari ẹgbẹ olukọ, NUT, ni ikilọ naa ti jẹyọ.
Ahmed ni ijọba ko ni i faaye gba ẹnikẹni lati ba orukọ ipinlẹ Kwara jẹ nipa ṣiṣe eru idanwo, nitori naa, ẹni tawọn agbofinro ba mu yoo da ara rẹ lẹbi.
O ni Gomina Abdulrahman Abdulrazaq ni lati san miliọnu ọgbọn naira tajọ to n ṣedanwo WAEC ni ki ipinlẹ Kwara san gẹgẹ bii owo itanran nitori ẹsun ṣiṣe eru idanwo lọdun 2019.
O kede pe awọn akẹkọọ JSS 3 yoo pada sẹnu ẹkọ wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to n bọ, lati gbaradi fun idanwo wọn to maa bẹrẹ loṣu kẹsan-an, ọdun yii.
Awọn aṣoju ANCOPSS, Toyin Abdullahi, ati ti awọn oludasilẹ ileewe aladaani, Dokita Adetunji Abdulrahman, ṣeleri fun ijọba lati tẹle gbogbo ilana ofin lasiko idanwo naa.