Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Eeyan marun-un ni ajọ ẹṣọ oju popo, FRSC, fidi ẹ mulẹ pe wọn doloogbe lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu kejila, ọdun 2021 yii, ninu ijamba mọto to waye loju ọna Agọ-Iwoye-Ibadan, Arebi, keeyan too de Abule Mamu, nipinlẹ Ogun.
Yatọ sawọn to ku, eeyan mẹfa ni wọn tun fidi ẹ mulẹ pe wọn fara pa.
Ọkọ Opel Safira to ni nọmba FN 73 APP ati bọọsi Mazda akero ti nọmba tiẹ jẹ FST 877 YC, ni ijamba ọhun kan.
Nnkan bii aago kan ọsan ku iṣẹju mẹrin ni ijamba naa ṣẹlẹ gẹgẹ bi Kọmandanti Ahmed Umar ti i ṣe ọga FRSC Ogun ṣe sọ.
O ṣalaye pe awakọ to wa bọọsi Mazda lo n sare buruku, oun lo fẹẹ ya Opel silẹ ti ijamba fi ṣẹlẹ, ti eeyan marun-un fi ku lẹsẹkẹsẹ.
Umar tẹsiwaju pe inu ọkọ Mazda to wa iwakuwa naa lawọn to ku ọhun wa, o ni ọkunrin mẹta ni wọn, obinrin meji.
Ileewosan Jẹnẹra Ijẹbu-Ode ni wọn ko awọn mẹfa to ṣeṣe lọ, mọṣuari ibẹ naa ni wọn si ko awọn to doloogbe si.
Fun ẹkunrẹrẹ alaye nipa ijamba ọhun, ileeṣẹ FRSC to wa l’Agọ-Iwoye ni wọn ni ki ẹbi awọn to padanu eeyan wọn lọ.