Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ti gba Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, niyanju lati ma ṣe ṣatilẹyin fun eyikeyii ninu awọn oloṣelu ti wọn n wa ipo bayii.
Ọbasanjọ sọ pe baba gbogbo iran Yoruba, lai fi ti ẹsin tabi ẹgbẹ oṣelu ṣe, ni Ọba Adeyẹye, o si gbọdọ gba gbogbo oloṣelu mọra lai dẹyẹ si ẹnikẹni.
Nibi ayẹyẹ kan ti Ọọni ti fi Alakooso apapọ Tropical Agriculture (IITA) to wa niluu Ibadan, Dokita Nteranya Sanginga, joye Afurugbin Ọla ti Ifẹ, eleyii to waye laafin Ọọni lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii ni Oloye Ọbasanjọ ti sọrọ yii.
Ọbasanjọ ṣalaye pe gbogbo oriade nilẹ Yoruba ko gbọdọ kede atilẹyin fun oloṣelu kankan nita gbangba. O sọ fun Ọọni, ni pataki, pe adura rẹ nikan ni awọn oloṣelu ti wọn ba wa si aafin rẹ nilo.
Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ọba o gbọdọ ṣe oṣelu, gbogbo oloṣelu lo jẹ ti ọba. Ẹnikẹni to ba fẹẹ dupo, yala ipo aarẹ tabi ipo gomina, ni wọn a maa wa sibi fun atilẹyin, ṣe ni ki ẹ gbadura fun wọn, ki wọn maa lọ.
“Awọn ti wọn n wa sọdọ yin lonii fun ojurere, to ba jẹ pe bi wọn ṣe fẹ ni, ko wu wọn ki ẹ de ori itẹ yii, ṣugbọn mo fẹran ẹmi idariji ti ẹ ni. Ni temi o, gbọingbọin ni ma a maa duro ti yin nigba gbogbo.”
Lori oye ti Ọọni fi Dokita Sanginga jẹ, Oloye Ọbasanjọ ṣalaye pe ika to tọ simu gan-an ni kabiesi fi re e, nitori ọjọ ti pẹ ti awọn mọlẹbi naa ti fi ara wọn jin fun idagbasoke iṣẹ agbẹ ati ipese ounjẹ ni Afrika.
Ninu ọrọ tirẹ, Ọba Ogunwusi gbadura fun Oloye Sanginga atiyawo rẹ, o ni ọrọ iṣọkan ilẹ Afrika ki i ṣe awada rara, gbogbo eniyan ni yoo si ṣiṣẹ fun idagbasoke rẹ.
Lara awọn ti wọn wa nibi ayẹyẹ naa ni aṣoju Aarẹ orileede Democratic Republic of Congo, gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Rasheed Ladọja atawọn alejo miiran.