Kọmiṣanna ọlọpaa tuntun bẹrẹ iṣẹ l’Ondo

Kọmiṣanna ọlọpaa tuntun bẹrẹ iṣẹ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọsẹ ta a wa yii lawọn eeyan ipinlẹ Ondo yoo gbalejo kọmisanna ọlọpaa tuntun ti ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ-ede yii ṣẹṣẹ fi ṣọwọ si ipinlẹ Ondo.

Ni ibamu pẹlu iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ, Ọgbẹni Oyediran Adesọye Oyeyẹmi ni wọn yan lati waa rọpo Ọgbẹni Bọlaji Amidu Salami ẹni to ṣẹṣẹ fẹyinti lẹnu iṣẹ ọlọpaa lọsẹ to kọja.

Ọgbẹni Oyeyẹmi ni wọn lo kẹkọọ gboye ni Yunifasiti Ibadan, to si wọ iṣẹ ọlọpaa lọdun 1990. O ti ṣiṣẹ takuntakun lawọn ipinlẹ bii Edo, Ogun, Ọyọ, Ebonyi ati Akwa-Ibom.

Ileesẹ ọkọ oju-irin, eyi ta a mọ si Reluwee, lo ti ṣiṣẹ gẹgẹ bii kọmisanna ki wọn too gbe e kuro nibẹ wa si ipinlẹ Ondo.

Ọga agba patapata fawọn ọlọpaa,  Usman Alkali, ti rọ kọmisanna tuntun ọhun lati ṣiṣẹ takuntakun fun alaafia gbogbo eeyan ipinlẹ Ondo.

 

Leave a Reply