Jijẹ ọmọ Naijiria pe mi ju jijẹ ọmọ orilẹ-ede Olominira Yoruba lọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ko figba kankan ri fara mọ ilẹ Olominira Yoruba ti wọn n pe ni Yoruba Nation, gbogbo igba ti aaye ba ti wa fun un lati sọ eyi di mimọ ni baba naa maa n sọ ọ. O si tun ti sọ bẹẹ laipẹ yii, o ni laelae, oun ko ni i ba wọn ṣatilẹyin fun Yoruba Nation, ki Naijiria duro lodidi loun n ṣe.

Nibi apero kan to waye laipẹ yii, eyi ti Global Peace Foundation ati Vision Africa gbe kalẹ ni Ọbasanjọ ti sọ pe, “Mi o ba wọn lo ohun to n jẹ Yoruba Nation ri ti mo ba n sọrọ, mi o si ni i ba wọn lo o, nitori mo gbagbọ pe bi mo ṣe jẹ ọmọ Naijiria ju bi mo ṣe jẹ ọmọ Yoruba lọ, ko si si eyi to yẹ ko dira wọn lọwọ ninu mejeeji.

“Ni temi, bi mo ṣe jẹ ọmọ Naijiria ṣe pataki, nitori jijẹ ọmọ Naijiria pe mi ju jijẹ ọmọ orilẹ-ede Olominira Yoruba lọ, mo si nigbagbọ pe bo ṣe yẹ ko ri lara gbogbo wa niyẹn.

‘‘Ki lo de tibi ti wọn ti bi mi yoo ṣe jẹ idena fun mi gẹgẹ bii eeyan, ati gẹgẹ bii ọmọ Naijiria.”

Bayii ni Oloye Ọbasanjọ beere. O tẹsiwaju pe oore wa ninu ki Naijiria duro lodidi ju ko tuka lọ.

Aarẹ tẹlẹ naa sọ pe ohun to da wa pọ gẹgẹ bii eeyan naa ni Naijiria, orilẹ-ede naa la mọ bii ilẹ wa, ti ẹya gbogbo si wa nibẹ. Fun idi eyi, omi la kọkọ n tẹ ka too tẹ yanrin ni Ọbasanjọ wi, Naijiria lo ṣagba Yoruba Nation. O loun ko ni i bawọn lọwọ si ijangbara ipinya tawọn kan n beere fun, labẹ bo ti wu ko ri.

Leave a Reply