Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Oṣerebinrin arẹwa nni, Funmi Awẹlẹwa, tawọn eeyan mọ si Mọrili, ko fi ọrọ sabẹ ahọn sọ l’Ọjọbọ to kọja yii, kedere lo sọ ẹdun ọkan rẹ soju opo Instagraamu, nigba to n ṣalaye bi oju iya rẹ ṣe ti fọ to si jẹ pe aisan tun n ṣe mama to bi i ṣe fọ, eyi to n mu ibanujẹ ọkan nla ba a.
Mọrili ṣalaye pe aarẹ kan lo ṣe mama oun to fi di pe oju rẹ fọ. O ni irora ti iya naa n la kọja ko ṣee ṣalaye, o si maa n ba oun lọkan jẹ lati ri mama naa ninu inira to n la kọja.
Bi Funmi Awẹlẹwa ṣe kọ ọrọ naa ree:
“Awọn oṣu diẹ sẹyin to kọja yii lagbara fun mi gan-an, nigba to tiẹ ya, mi o le ronu mọ, mi o si mọ bi mo ṣe le ṣalaye bo ṣe n ṣe mi. Nnkan ibanujẹ nla ni keeyan maa wo iya rẹ ko maa la inira iru eyi kọja, bẹẹ o tun ti pẹ ti oju wọn ti fọ o.
“Bi mo ṣe n ri wọn ninu inira nla yẹn n ba mi lọkan jẹ, o si n ṣakoba fun gbogbo ohun ti mo n ṣe. O ṣakoba fun iṣẹ mi, lati oṣu keje, ọdun to kọja, ni mi o ti lọ soko ere mọ, niṣe ni mo gbaju mọ itọju wọn. O tun ṣakoba fun okoowo mi naa, nitori mo kan n lọ lati ileewosan kan sikeji ni.
“Mo kọ ọpọlọpọ ode ariya silẹ, mi o lọ, awọn ẹlẹgbẹ mi kan ro pe ti igberaga ni, pe mi o fẹẹ ba wọn ṣe ni. Wọn o mọ pe mo ni ohun to n ba mi ja labẹ aṣọ, eyi ti i ṣe ailera iya mi.
“Kin ni idunnu mi nigba tiyaa mi ba wa ninu inira nla. Mo fẹran mọlẹbi mi, mi o si ki i fi wọn ṣere. Ṣugbọn ohun to n ṣẹlẹ si mi lati bii oṣu diẹ ti yi ọpọlọpọ nnkan pada lara mi. Ṣe ti owo ti mo n na lojumọ ni mo fẹẹ sọ ni, abi ti oogun oniwakati meji-meji. Hmmm. O daa.”
Nipari ẹdun ọkan rẹ to sọ sita yii, Funmi Awẹlẹwa ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe iya naa ṣi wa, ko ti i ku. O ni ẹbẹ kan toun n wulẹ n bẹ Ọlọrun ni pe ko jọwọ, ko jẹ ki iya oun tiẹ riran lẹẹkan si i, koda bi ko ju fun iṣẹju marun-un lọ, k’oju naa la, kiyaa si ri ohun toun ti da laye oun.
O waa dupẹ lọwo awọn ti wọn ti kan si i lọdun tuntun yii, bẹẹ lo ni oun atawọn ẹbi oun ti ṣetan lati gba oore ti n bẹ ninu ọdun tuntun naa.