Alaga ẹgbẹ ọlọkada yii ji ọkada gbe n’Iworoko Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọkunrin ẹni ọdun marundinlaaadọta kan, Ọgbẹni Oluṣẹgun Ayẹni to tun jẹ alaga ẹgbẹ ọlọkada ni agbegbe Iworoko-Ekiti, ti wa nile-ẹjọ Majisreeti kan bayii l’Ado-Ekiti, nibi to ti n sọ tẹnu rẹ lori ẹsun pe o ji ọkada gbe ti wọn fi kan an.

Ọkunrin yii lawọn ọlọpaa gbe wa sile-ẹjọ naa pẹlu ẹsun ole jija ati igbimọ-pọ lati fọle onile.

Agbefọba ile-ẹjọ naa, Isipẹkitọ Johnson Okunade, ṣalaye pe ọdaran naa ṣe ẹṣẹ yii ni Iworoko-Ekiti, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun to kọja yii, ni deede aago mẹrin idaji ọjọ naa.

Okunade sọ pe ọdaran naa ji ọkada kan ati awọn irinṣẹ bii ada, ọkọ ati ẹrọ ti wọn fi n fin oko, ti gbogbo owo rẹ din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (N480) Naira, to jẹ dukia Ọgbẹni Olaẹgbọn Ọladimeji.

O ṣalaye pe ọdaran naa tun ji waya ti wọn fi n fa ina sile ati awon ohun eelo ti wọn fi n ṣe ina ti gbogbo iye owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna irinwo ataabọ Naira (N450,000) to jẹ dukia Ọgbẹni Akinlẹyẹ Ojo.

Gbogbo ẹsẹ wọnyi lo juwe gẹgẹ bii ohun to lodi sofin ole jija to jẹ ofin ipinlẹ Ekiti ti wọn kọ lọdun 2012.

Ṣaaju ni agbefọba naa ti tọrọ aaye ranpẹ lọwọ ile-ẹjọ naa pe ki wọn fun oun laaye ki oun le ko ẹlẹrii jọ, ati lati le ko wọn wa si ile-ẹjọ.

Ṣugbọn agbẹjọro fun ọdaran naa, Ọgbẹni Emmanuel Sunmonu, bẹ ile-ẹjọ naa pe ko yọnda onibaara oun naa foun pẹlu ileri pe ko ni i sa lọ.

Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Abdulhamid Lawal fun ọdaran naa ni iyọnda pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira ati oniduuro meji.

Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ siwaju di ọjọ keje, oṣu keji, ọdun 2022.

 

Leave a Reply