Ọpọ fara pa nibi ija Fulani darandaran atawọn agbẹ ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọpọ lo fara pa yannayanna lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, lasiko tawọn Fulani darandaran atawọn agbẹ doju ija kọra wọn niluu Alapa, ijọba ijọba ibilẹ Asa, nipinlẹ Kwara.

Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ajọ ẹsọ alaabo ṣifu difẹnsi, ẹka ti ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Babawale Zaid Afolabi, fi sita lo ti sọ pe ọfiisi ajọ naa to wa niluu Alapa, lo gba ipe pajawiri pe awọn Fulani darandaran ati awọn agbẹ ti da rogbodiyan silẹ laarin ara wọn latari pe Fulani darandaran kan da maaluu sinu oko agbẹ kan, Alaparo Tunde, eyi to mu ki oun ati awọn ọmọ rẹ meji, Saheed Tunde ati Taofeek Tunde,  kọju ija si Fulani darandaran kan ti orukọ rẹ n jẹ Haruna Adamu, ti wahala si bẹ silẹ laarin wọn.

O tẹsiwaju pe adari ajọ NSCDC, Ọgbẹni Makinde Ayinla, lo paṣẹ pe ki awọn ẹsọ ajọ naa lọọ yanju aawọ naa, ṣugbọn ki wọn too de sibi iṣẹlẹ naa, wọn ti ṣa ara wọn niṣaakuṣaa, ti Fulani darandaran ati awọn ọmọ agbẹ mejeeji si fara pa yannayanna. O fi kun un pe wọn ti ko wọn lọ si ileewosan to sun mọ agbegbe naa fun itọju to peye, ti alaafia si ti jọba ni ilu naa, ti iwadii si n lọ lori iṣẹlẹ ọhun.

Leave a Reply