Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti kede pe ọwọ ti tẹ awọn janduku meji ti wọn n ṣiṣẹ fawọn oloṣelu, ti wọn si n da agbegbe Ijero-Ekiti, nijọba ibilẹ Ijero, nipinlẹ Ekiti, ru.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa, Ọgbẹni Sunday Abutu, ṣalaye pe awọn afunrasi meji naa ti ko darukọ wọn, ṣugbọn ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mejilelogun si ogun lọ ni ọwọ ẹka to n gbogun ti ẹsun ole jija ti teṣan to wa ni Ijero-Ekiti tẹ nigba ti wọn ṣe ọtẹlẹmuye ati ayẹwo ni agbegbe naa.
O sọ pe ṣe ni awọn agbofinro naa sadeede ri bọọsi akero kan to wa lẹgbẹẹ ọna, ti awọn ọdọ bii mejila si wa ninu ọkọ naa. Bi awọn ọlọpaa ṣe sun mọ idi ọkọ naa ni awọn janduku yii bẹ sigbo, ti wọn si fẹsẹ fẹ ẹ. Awọn ọlọpaa le wọn wọnu igbo, ọwọ wọn si tẹ meji lara wọn.
Ṣugbọn nigba ti wọn ṣe ayẹwo inu ọkọ naa, ibọn agbelẹrọ mẹrin, ibọn ilewọ kekere kan ati ọta ibọn meje pẹlu igbo ti wọn di sinu ọra, bakan naa ni wọn ba oogun oriṣiiriṣii ninu bọọsi naa.
O ṣalaye pe awọn meji ti ọwọ tẹ naa ti wa ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni oju ọna to lọ si ilu Iyin-Ekiti, ti wọn si ti n sọ tẹnu wọn.
O ṣeleri pe awọn odaran naa yoo foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari.