Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọgọọrọ Hausa atawọn Fulani darandaran to wa lagbegbe Igbọkọda, nijọba ibilẹ Ilajẹ, ni wọn ti n sa kuro ni ibugbe wọn nitori ibẹru pe awọn araalu le waa gbẹsan iku obinrin oniṣowo kan, Joguntan Roseline, ti wọn pa lẹyin ti wọn fipa ba a sun tan lopin ọsẹ to kọja.
Oloogbe ọhun ni wọn ba oku rẹ ninu agbara ẹjẹ ninu igbo niluu Zion, nitosi Igbọkọda.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, eeso tita ni Roseline yan laayo, oun ati ọmọ rẹ kan ni wọn si jọ jade lọjọ naa lati lọọ ra eeso wale fun tita gẹgẹ bii iṣe wọn.
Lẹyin to ra ọja tan lo di ẹru diẹ sinu apẹrẹ, to si gbe e le ọmọ rẹ lori pe ko maa niṣo nile.
Nigba ti ọmọ de ile to reti iya rẹ titi ti ko rẹni to jọ ọ lo lọọ fọrọ naa to awọn aladuugbo kan leti.
Wọn ko fi bẹẹ wa abilekọ ọhun jinna ti wọn fi ba oku rẹ nibi ti wọn pa a si nitosi ibi tawọn Hausa ati Fulani fi ṣe ibudo lagbegbe Zion.
Ẹnikan to b’ALAROYE sọrọ, ṣugbọn to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ni ki i ṣe igba akọkọ ree ti iru iṣẹlẹ bẹẹ maa waye.
O ni eyi lo fu awọn eeyan Oke-Ọya naa lara ti wọn fi tete n sa kuro ni kete tawọn eeyan ṣawari oku Roseline layiika wọn. O ṣalaye pe ipo ti awọn ba oku rẹ fihan pe ki i ṣe ọkunrin kan tabi meji ni wọn fipa ba a lo pọ ko too di pe wọn la nnkan mọ ọn lori lẹyin ti wọn tẹ ifẹ inu wọn tan.
Alukoro fun igbimọ to n ri sọrọ aabo lagbegbe Ilajẹ, Emorioloye Owolemi, sọ pe o ti to asiko fun ijọba lati tete gbe igbesẹ lori bi opin yoo ṣe de ba bi wọn ṣe n pa awọn eeyan Ilajẹ nipakupa kọrọ naa too pẹ ju.
O ni lara awọn nnkan to le din ọrọ iṣekupani ku nijọba ibilẹ Ilajẹ ni kijọba ro awọn Fijilante lagbara, eyi ti wọn yoo fi le koju awọn ipenija eto aabo agbegbe naa.
Bakan naa lo tun parọwa si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo lati ṣawari awọn oniṣẹẹbi to ran Roseline sọrun ọsan gangan ni kiakia, ki wọn le jiya to tọ labẹ ofin.