Ọlawale Ajao, Ibadan
Lati le mu idagbasoke ba ede Yoruba, gbogbo awọn to wa nidii akoso eto ẹkọ kaakiri ẹkun Iwọ-Oorun Guusu orileede yii, titi de ipinlẹ Kwara ati Kogi, yoo ṣepade n’Ibadan lọjọ kẹta, oṣu kẹta, ọdun yii.
Ipade ọhun, to jẹ akọkọ iru ẹ ninu itan, lajọ Ibudo Agbaye fun gbogbo ọmọ Yoruba (Yoruba World Centre) ṣagbatẹru rẹ pẹlu atilẹyin O’dua Investment Plc (ileeṣẹ to jẹ tawọn ijọba ipinlẹ Yoruba gbogbo) ati DAWN Commission, iyẹn ajọ to n mojuto eto idagbasoke ilẹ Yoruba.
Ta o ba gbagbe, ninu oṣu kọkanla, ọdun 2021, ni Igbakeji Aarẹ orileede yii, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ṣe ifilọlẹ ajọ International Council for Yoruba Arts and Culture (INCEYAC) to bi World Centre, ninu ọgba Fasiti Ibadan.
Idije imọ Ede Yoruba to le sọ awọn akẹkọọ ileewe girama di miliọnia, eyi ti ajọ Ibudo Yoruba Agbaye yii gbe kalẹ ni wọn fẹẹ tori ẹ ṣepade naa.
Lara awọn ti yoo kopa nibi ipade ọhun ni awọn alaga kansu gbogbo kaakiri awọn ipinlẹ ilẹ Yoruba titi dori awọn alaga igbimọ eto ẹkọ lawọn ileegbimọ aṣofin gbogbo kaakiri ẹkun Iwọ-Oorun ilẹ yii.
Bakan naa lawọn aarẹ atawọn akọwe ẹgbẹ awọn olukọ Yoruba kaakiri awọn ileewe girama ilẹ Yoruba gbogbo, pẹlu awọn onimọ ede Yoruba nilẹ yii (Yoruba Studies Association) atawọn adari Ẹgbẹ Akọmọlede Yoruba yoo kopa nibi ipade naa pẹlu oludari ileeṣẹ atẹwe nni, University Press Limited.
Ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin, Oludari ajọ Yoruba World Centre, Ọgbẹni Alao Adedayọ, fidi ẹ mulẹ pe “gbogbo awọn alakooso eto ẹkọ wọnyi la ti ri. Inu gbogbo wọn lo dun pe irufẹ ipade bayii fẹẹ waye, ti wọn si fifẹ han lati kopa ninu ẹ nitori idagbasoke ti eto yii yoo mu ba ede Yoruba, iṣẹ ti yoo pese fawọn ọdọ ati nitori iṣọkan pẹlu ibagbepọ alaafia ti yoo mu ba awọn ẹya orile-ede yii.
“Idije imọ asọni-di-miliọnia ti wọn fẹẹ tori ẹ ṣepade yii ni yoo maa ṣe koriya nla fun akitiyan awọn ọmọ Yoruba atawọn ileeṣẹ aladaani ilẹ Yoruba ti wọn ba n gbiyanju lati mu ede Yoruba goke agba.”