Faith Adebọla
Minisita tẹlẹ fun eto omi, Abilekọ Sarah Ochekpe, ti rẹwọn he, ọdun mẹta nile-ẹjọ giga apapọ kan to fikalẹ siluu Jos, nipinlẹ Plateau, sọ obinrin naa si, latari pe ọwọ rẹ ko mọ nidii owo ọba ti wọn ṣe baṣubaṣu lasiko to n ṣe minisita ilẹ wa.
Bakan naa nile-ẹjọ tun paṣẹ pe kawọn meji mi-in, Ọgbẹni Raymond Dabo, to figba kan ṣe adele alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) nipinlẹ Plateau, ati Ọgbẹni Sunday Leo Evan ti i ṣe igbakeji oludari igbimọ ipolongo ibo fun Goodluck ati Sambo lọdun 2015, fẹwọn ọdun mẹta mẹta jura, tori wọn jọ huwa palapala naa ni.
Ẹsun mẹta ọtọọtọ ni ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC, ka sawọn ọdaran naa lẹsẹ. Awọn ẹsun naa da lori irinwo miliọnu Naira ati aabọ (N450 million) ti wọn gba lọdun 2015, ti wọn ko si le ṣalaye nipa bowo naa ṣe rin.
Ninu atẹjade kan ti ajọ EFCC ti kọkọ ṣalaye awọn ẹsun wọnyi, wọn ni lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2015, iwadii awọn fihan pe banki Fidelity gba owo ti wọn fẹsun rẹ kan wọn naa jade lati banki apapọ ilẹ wa (CBN), o si ko o fawọn ọdaran mẹtẹẹta yii, lati fi ṣeto idibo ọdun 2015, wọn ni minisita epo rọbi, Abilekọ Diezani Allinson-Madueke, lo lo orukọ awọn ileeṣẹ kan lati fowo naa ṣọwọ si wọn.
Loootọ lawọn ọdaran yii jẹwọ pe owo naa tẹ awọn lọwọ, amọ wọn ni Sẹnetọ Gyang Pwajok, to fẹẹ dupo gomina labẹ asia ẹgbẹ PDP lọdun naa lawọn ko o fun, ko le fi ṣeto idibo rẹ.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ H. M. Kurya, sọ pe awọn olujẹjọ naa ko ri ẹri kan mu jade lati fidi ẹ mulẹ pe loootọ ni wọn ko owo yii fun ẹni ti wọn lawọn ko o fun. O tun ni wọn jẹbi igbimọpọ lati gba owo to ju iye ti ofin to ka fifi owo nla ranṣẹ, ka leewọ.
O ni ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ fihan pe wọn jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn, o si paṣẹ pe ki ọkọọkan wọn lọọ fẹwọn ọdun kọọkan jura lori ẹsun kọọkan, eyi to tumọ si pe ẹni kọọkan yoo ṣẹwọn ọdun mẹta gbako.
Ṣugbọn adajọ naa oun fun wọn laaye lati sanwo itanran miliọnu kan Naira fun ọkọọkan wọn, bi wọn ko ba fẹẹ ṣẹwọn.