Ọṣinbajo ṣi oriṣiiriṣii iṣẹ akanṣe nipinlẹ Borno, o ṣabẹwo sawọn Boko Haram to ti ronupiwada

Jọkẹ Amọri

Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, ti ṣeleri pe ijọba ti ṣetan lati ri si ọrọ awọn Boko Haram to ronupiwada nipa ṣiṣe atilẹyin fun wọn lori okoowo to bofin mu ti wọn ba ni lọkan lati ṣe. O ni ṣiṣe iru iṣẹ to tọna bẹẹ yoo jẹ ki wọn bẹrẹ si i gbe igbe aye ọtun. O fi kun un pe ijọba yoo ran wọn lọwọ ni gbogbo ọna to ba yẹ lati pese ibi ti wọn yoo maa gbe, ati iṣẹ ọwọ to bofin mu ti wọn yoo maa ṣe lati le tọju ara wọn, tawọn paapaa yoo si di ẹni to n gbaayan ṣiṣẹ lawujọ.

O sọrọ yii l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni Hajj Camp, niluu Maiduguri, nipinlẹ Borno, lasiko abẹwo to ṣe si ipinlẹ ọhun, nibi to ti ṣe ifilọlẹ awọn iṣẹ akanṣe lọlọkan-o-jọkan ti Gomina ipinlẹ naa, Babagana Umara Zulum, ṣe.

Ọṣinbajo, ẹni ti Minisita fọrọ ileeṣẹ, okoowo ati idaṣẹ silẹ, Ambasadọ Maryam Katagun, ati Minisita feto ọgbin to tun jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Borno, Baba Sheuri, atawọn aṣofin ipinlẹ naa kọwọọrin pẹlu rẹ ni wọn ṣi awọn iṣẹ akanṣe loriṣiiriṣii. Bakan naa ni wọn ṣefilọlẹ ileewe igbalode ti wọn kọ lorukọ ọkan pataki ninu awọn ọmo ipinlẹ naa, Alaaji Mai Deribe. Bẹẹ ni awọn oju ọna ti wọn ṣẹṣẹ ṣe ko gbẹyin ninu awọn iṣẹ akanṣe ti Igbakeji Aarẹ ṣiṣọ loju wọn.

Lasiko abẹwo naa lo ya si ibi ti wọn ṣe awọn ọmọ Boko Haram to ti ronupiwada lọjọ si, to si sọ fun wọn pe ijọba ko gbagbe wọn, o waa rọ wọn ki wọn ki wọn ni suuru, ki wọn si bọwọ fun ofin ilẹ wa.

‘Ọṣinbajo ni, mo fẹẹ fi da yin loju pe a maa ṣiṣẹ pọ pẹlu yin, awọn to le ran wa lọwọ, awọn eleto aabo, ki i ṣe lati ri i pe a mojuto awọn iṣẹ ounjẹ oojọ yin nikan, ṣugbọn lati ri i pe ẹ wa ni ayika ti aabo wa, ti ẹ si ti le maa ṣe awọn iṣẹ yin bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ lawujọ.

Bakan naa lo ṣabẹwo si aafin Sheu Borno, Alaaji Abubakar Ibn Umar Garbi Elkanemi, nibi to ti ki kabiyesi, to si gboṣuba fun gomina ana nipinlẹ naa, Kashim Shettima, ati eyi to wa nibẹ bayii, Gomina Zulum.

Bakan naa lo lu gomina naa lọgọ ẹnu fun iṣẹ takuntakun to n ṣe nipinlẹ Borno. O ni o ṣee ṣẹ lati ṣe awọn ohun to daa, ni pataki ju lọ, ta a ba ni awọn adari bii Zulum.

Lasiko abẹwo naa lo tun yọju si ileewe awọn ọmọ alailobii to kọ sipinlẹ naa lọdun 2017, eyi ti wọn pe ni Yẹmi  Ọṣinbajo Orphanage School to wa loju ọna Maiduguru si Biu, nibi ti awọn akẹkọọ to le lẹẹẹdẹgbẹta wa.

 

Leave a Reply