Ọrẹoluwa Adedeji
Ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa to ṣẹṣẹ ṣegbeyawo laipẹ yii, Mercy Aigbe, ko le pa idunnu rẹ mọra nigba to ri fọto oun ati ọkọ rẹ lẹyin Magasinni kan ti wọn n pe ni Media Room Hub. Niṣe lo gbe e si ori Instagraamu rẹ bayii pe ‘‘Igba akọkọ niyi ti wọn yoo gbe awa mejeeji si ẹyin Magasinni.
Ki i ṣe pe wọn gbe wọn si ẹyin Magasinni lasan, awọn oniroyin naa fọrọ wa Mercy ati ọkọ rẹ lẹnu wo, ti oṣere naa ati ọkọ to fẹ, Kazeem Adeoti naa si sọrọ nipa igbeyawo wọn ati ohun ti ọpọlọpọ ko mọ nipa rẹ.
Mercy ṣalaye pe oun ko tori owo fẹ ọkunrin makẹta to n gbe awọn oṣere jade naa, bẹẹ loun ko si gba a lọwọ ẹnikẹni. O ni agbalagba loun, oun ki i ṣe ọmọde, oun si mọ ohun to daa fun oun, ati pe ko si ootọ ninu ọrọ tawọn kan n sọ kiri pe oun gba ọkọ ọlọkọ. O ni Musulumi loun, gẹgẹ bii Musulumi, oun lanfaani lati fẹ ẹni to ti niyawo nile, ko si si ohun ti oju ko ri ri ninu pe oun fẹ ẹni to ti niyawo sile.
Mercy ni, ‘‘Mo kan fẹẹ bẹ gbogbo ọmọ Naijiria pe emi kọ ni ẹni akọkọ ti yoo jẹ iyawo keji lọọdẹ ọkunrin. Ohun ti mo fẹ ni mo yan, inu mi si dun si i. Ẹ jọwọ, ẹ fi mi silẹ, ẹ jẹ ki n gbadun igbeyawo mi. Ti ẹ ba le ba mi yọ, ẹ ba mi yọ, ti ẹ ko ba si le ba mi yọ, ẹ wa iṣẹ gbe fun ara yin.’’
O ni nigba ti igbeyawo oun pẹlu Lanre Gentry daru, oun ti pinnu lọkan oun pe iṣẹ oun atawọn ọmọ oun loun maa gbaju mọ. Ṣugbọn nigba toun ṣalabaapade ọkunrin makẹta yii, o yi ero ati ipinnu oun pada pẹlu bo ṣe n ṣe si oun.
Mercy ni, ‘‘Adeoti ti mu ọpọlọpọ ayọ, alaafia ati idunnu wa sinu aye mi. Gbogbo igba ni mo maa n sọ fun un pe eeyan daadaa ni. Nigba to si dẹnu ifẹ kọ mi, mo pinnu lati gbiyanju rẹ wo pẹlu ipinnu pe ibi yii ni mo de duro, ko si pe mo tun fẹẹ lọkọ kankan mọ lẹyin rẹ. Mo si dupẹ pe mo ṣe ipinnu naa. Ọkọ mi jẹ ẹnikan to daa, o si n ṣatilẹyin fun mi. Mi o fẹ ẹ nitori owo rẹ, ṣugbọn o n fun mi ni ayọ ati ifọkanbalẹ.’’
Nigba to n ṣalaye bi wọn ṣe pade, ọkọ arẹwa oṣere yii sọ pe iṣẹ okoowo lo pa awọn pọ, o ni oṣere naa jẹ olotitọ, ohun to si ya oun lẹnu nipa rẹ ni bo ṣe da owo ti awọn na ku lori fiimu kan to ṣe lọdọ oun foun. O ni eleyii ya oun lẹnu, latigba naa lawọn si ti jọ n ṣowo pọ ko too di pe ọrọ fifẹ wọ ọ.
Bakan naa ni ọkọ Mercy to tun n jẹ Minnah bayii sọ pe loootọ loun ti ni iyawo kan tẹlẹ, ṣugbọn gẹgẹ bii Musulumi, oun ni anfaani lati fẹ iyawo keji, eyi ni oun si ṣe. O fi kun un pe ọpọlọpọ ọkunrin mi-in ni wọn jẹ alagabagebe, ti wọn yoo maa ko obinrin kiri, ti wọn ko si ni i laya lati gbe iru igbesẹ ti oun gbe yii. O ni to ba ya lọjọ iwaju, gbogbo eeyan ni yoo maa gboṣuba fun oun pe oun jade lati gbe igbesẹ fifẹ iyawo keji yii to jẹ ohun ti Ọlọrun dunnu si ni, yatọ si ki oun maa yan ale kiri.
Bakan naa lo fi kun un pe ko si wahala kankan nile oun. O ni iyawo oun wa ni orileede Amẹrika, iṣẹ oun si wa ni Naijiria, eyi lo fa a toun fi maa n lọ si Amẹrika diẹ, toun yoo si tun wa ni Naijiria fun iṣẹ oun.