Gbenga Amos
Gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ipe ti wọn fi ṣọwọ si gbogbo awọn alaga ẹgbẹ oṣelu APC, ti ko ba si ayipada ojiji, aago mẹjọ aabọ owurọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta yii, ni Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, yoo ṣepade pataki kan pẹlu gbogbo awọn alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) lawọn ipinlẹ kaakiri ilẹ wa, pẹlu bi wọn ṣe ti n palẹmọ lati kede erongba rẹ lati jade dupo aarẹ lọdun 2023.
Ipade naa yoo waye nile ijọba, ni gbọngan apero ọfiisi Igbakeji Aarẹ.
Awọn alaga naa maa kọkọ pade ni Otẹẹli Barcelona, to wa nitosi ile ijọba, ibẹ lẹsẹ wọn ti maa pe jọ, ni aago mẹjọ aarọ, ki wọn too lọọ pade Ọṣinbajo.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọ ohun ti ipade naa da le ninu iwe wọn, eyi ti Alaaji Bukar Dalori ti i ṣe alaga APC nipinlẹ Borno, ati alaga ẹgbẹ awọn alaga ipinlẹ ẹgbẹ APC, buwọ lu, wọn ni Ọṣinbajo maa lo anfaani ipade naa lati ba wọn sọrọ lori erongba rẹ lati dupo aarẹ.
Ẹ ranti pe ọsẹ to kọja yii ni adele alaga apapọ fun igbimọ kiateka ti ẹgbẹ APC, Gomina ipinlẹ Niger, Sani Bello, ṣebura fawọn alaga ti wọn ṣẹṣẹ yan sipo naa, l’Abuja.
Aipẹ yii si ni agbẹnuṣọ fun igbakeji aarẹ sọ pe ọga oun maa too kede erongba rẹ faye gbọ, boya yoo jade dupo aarẹ tabi ko ni i ṣe bẹẹ.