NDLEA mu oludasilẹ ijọ pẹlu kokeeni ni papakọ ofurufu Muritala l’Ekoo

Jọkẹ Amọri

Isọji ita gbangba ọlọsẹ mẹta ni Oludasile ijọ Christ Living Hope Church, Ugochkwu Ekwem, loun n lọọ ṣe ni orileede Kenya to fi gba papakọ ofurufu ilu Eko lọ. Lara awọn ohun to gbe lọwọ to fi n fẹẹ rin irinajo naa ni awọn igi kan to jẹ mẹrindinlọgọta.

Nigba ti wọn ṣe ayẹwo si awọn igi ti ọkunrin ti ṣọọṣi rẹ wa ni Isuaniocha, lọna Mgbakwu, to wa ni Awka, nipinlẹ Anambra, to si tun ni ẹka ṣọọṣi rẹ niluu Eko ati Abuja yii ni wọn ri i pe kokeeni bii kilo mẹrindinlọgọta lo wa ninu awọn igi to ko lọwọ naa.

Nigba ti wọn si bi i ohun ti kokeeni n ṣe ninu awọn igi naa,  iranṣẹ Ọlọrun yii ni oun fẹẹ lo o lọhun-un ni.

Alukoro ajọ to n ri si gbigbe ati lilo oogun oloro, Femi Babafẹmi, lo sọ eyi di mimọ lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, pe lọjọ keje, oṣu Kẹta, ọdun yii, lọwọ tẹ ọkunrin to pera rẹ ni iranṣẹ Ọlọrun yii.

Lasiko ti wọn n ṣe ayẹwo awọn ero inu baaluu to n lọ si Nairobi to fẹẹ wọ baaluu Ethopia lọwọ tẹ oludasilẹ ijọ naa.

Bakan naa ni wọn mu arinrin-ajo kan, Nnakeanyi Chukwuka King, nigba to sọkalẹ ninu baaluu Ethopia kan to n bọ lati orileede Brazil.

Nigba ti wọn n yẹ ẹru rẹ wo ni wọn ba idi kokeeni bii ogoji (40) ti iwọn rẹ to kilo mẹwaa din diẹ (9.7kg) to di sinu ike ipara.

Ọjọ kẹta lẹyin eyi ni wọn tun mu arinrin-ajo kan to n lọ si orileede Italy, Ogbẹni Edo Blessing, baalu Ethopia yii loun naa wọ. Tramadol ati Flunitrazepam to le diẹ ni ẹgbẹrun kan, (2,090) ni wọn ka mọ ọn lọwọ. Ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Edo, to fi orileede Italy ṣe ibugbe yii naa jẹwọ pe oun loun ni awọn oogun naa.

Lọjọ yii kan naa ni wọn tun mu ọkan ninu awọn to maa n ba awọn eeyan fẹru ranṣẹ si oke okun, Rafiu Abass, ni ẹka NAHCO ni wọn ti mu un nigba to gbe ẹru kan to ni o n lọ sin London wa, to si jẹ pe igbo to din diẹ ni ogun kilo (19.15kg) ni wọn ba nibẹ.

Lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ni ọwọ ajọ NDLEA tun tẹ baba ẹni ọdun mẹtalelọgọta kan, Vincent Obimma, pẹlu iwọn kokeeni to to giraamu ọọdunrun ataabọ (350grams), kokeeni ati giraamu aadọjọ (150grams) lo ko pamọ sinu paali tọọṣi to n lọ si ilu Kano lati Apapa.

Bakan naa ni wọn mu ọkunrin kan toun naa maa n ṣowo oogun oloro, James Okenwa, ni Central Market, Kaduna. O jẹwọ pe oun loun ni ẹgbẹsan ati meje (1, 807) awọn oogun ikọ kan ti wọn gba lọwọ awọn kan ni too geeti. Lẹyin naa ni wọn ba igo oogun kan to to aadoje ati meji (152). O ni oun loun ni gbogbo awọn oogun naa.

Leave a Reply