Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, lọwọ tẹ obinrin afiniṣowo kan to n dibọn bii alarun ọpọ lagbegbe Kunlende, nijọba ibilẹ Guusu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.
ALAROYE gbọ pe awọn olugbe agbegbe naa fura si obinrin ọhun to mura bii were, to si gbe ẹru nla lọwọ, wọn tun ri i pẹlu arakunrin kan to wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ jiipu alawọ dudu kan, ṣugbọn iyẹn tete sa lọ. Wọn mu obinrin yii, nigba ti wọn tu ẹru rẹ wo ni wọn ba oniruuru aṣọ ileewe awọn ọmọ pẹlu ọpọlọpọ owo, awọn iwe ti awọn ọmọ ileewe fi n kọṣẹ, awọn kika ati bẹẹ bẹẹ lọ. Eyi lo mu ki wọn gba a mu, wọn ti lu u diẹ ki wọn too fa a le ọlọpaa lọwọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si ni ki wọn gbe arabinrin naa lọ si ileewosan ki wọn ṣe ayẹwo fun un boya loootọ lo ni arun ọpọ.