O ma ṣe o, ọsẹ kan lẹyin ti oṣere tiata yii ṣọjọọbi ni wọn ba oku ẹ loteẹli kan

Faith Adebọla

 “Kai, aye ma nika o! Lọjọ kejila, oṣu Kẹta, ọdun to kọja, a ṣayẹyẹ ọjọọbi ẹ tayọ-tayọ, ṣugbọn iku lo fi pari ayẹyẹ naa lọdun yii. Hunm, aye n doro o. Iwọ ọmọ jẹẹjẹ, to jẹ tẹrin-tọyaya lo fi n pade gbogbo eeyan to wa layiika ẹ, ko ni i daa fawọn ọdaju to da ẹmi ẹ legbodo yii o, bi ọba aye o ba ri wọn, ọba ọrun maa fiya jẹ wọn dandan ni. Veronica, sun un re o.”

Eyi ni ọkan ninu ọrọ aro tawọn eeyan fi kẹdun iku airotẹlẹ to pa oṣẹre tiata kan, Veronica Takor, nipinlẹ Benue, lọjọ Wẹsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Ba a ṣe gbọ, inu yara otẹẹli kan to wa lagbegbe Nyinma, niluu Makurdi, ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ naa ni wọn ti ba oku ọmọbinrin ti wọn ni ko ti i ju ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn lọ yii.

Wọn ni ọsẹ to kọja lọmọbinrin yii ṣayẹyẹ ọjọọbi ẹ ni otẹẹli naa, tawọn ọrẹ, mọlẹbi atawọn ololufẹ ẹ si ba a yọ, ti wọn ti wọn gbadun ara wọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Benue sọ pe awọn ti mu ẹni mẹta kan, ti ọkan ninu wọn jẹ oṣiṣẹ otẹẹli ti wọn ti ba oku oloogbe naa sahaamọ, awọn si ti bẹrẹ iwadii lori iku oloogbe naa.

Ẹkọ nipa awọn nnkan abẹmi ni Veronica kọ ni Fasiti Benue, o si gboye jade, ko too bẹrẹ iṣẹ tiata elede oyinbo.

Iṣẹlẹ yii ka ọrẹ rẹ kan, Timothy Zedekiah lara to fi kọ ọ soju opo fesibuuku rẹ pe: “Kin nile aye ja mọ gan-an. Kin nitumọ igbesi aye. Veronica Takor o si mọ, eeyan alaafia ti lọ. Ileeṣẹ Zefat Movies maa ṣaaro ẹ titi lae, ta lo maa waa rọpo ipa to o fẹẹ ko ninu fiimu ta a n ya lọwọ bayii. Idajọ ododo la fẹ lori iku yii o, ki awọn to pa ẹ bii ẹni pa adiẹ ma ṣe sinmi lọjọ aye wọn titi ti iku fi maa pa awọn naa danu laipẹ. Sun un re o.”

Leave a Reply