Ọlawale Ajao, Ibadan
Iwadii ti bẹrẹ lori bi awọn adigunjale kan ṣe ya wọ adugbo Ladeowo, ni Ọmi-Adio, niluu Ibadan, nipilẹ Ọyọ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ti wọn si pa awọn eeyan agbegbe naa mẹrin lasiko ti wọn lọọ ja awọn oni POS to wa ni adugbo naa lole.
ALAROYE gbọ pe ọkada ni awọn eeyan naa gbe wọ adugbo ọhun lalẹ ọjọ yii, bi wọn si ti debẹ ni wọn n wọ ọdọ awọn to n fi maṣinni sanwo ti wọn n pe ni POS, ti wọn si n gba owo lowọ wọn. Lasiko ti wọn n huwa laabi naa lọwọ lawọn eeyan ke si awọn ọlọpaa, ṣugbọn wọn ko yọju. Awọn araadugbo ti wọn gbọ nigba ti awọn eeyan naa n pariwo ni wọn gba ya awọn adigunjale naa. Niṣe ni awọn ọdaran ẹda naa da ibọn bolẹ, ti wọn si bẹrẹ si i rọjo rẹ lai bikita.
Niṣe ni gbogbo adugbo naa daru, ti onikaluku si n sa asala fun ẹmi rẹ. Lasiko ti wọn n yinbọn kikankikan lati fi le awọn eeyan sa, ki wọn si le raaye sa lọ yii ni wọn pa awọn eeyan agbegbe naa mẹrin.
A gbọ pe awọn ọlọpaa Ọmi-Adio ti wọn pe lalẹ ọjọ Ẹti ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ ko yọju, ọjọ Abamẹta, Satide, ni wọn too wa si agbegbe naa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Adewale Ọṣifẹsọ, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.