Faith Adebọla
“Emi ni mo pariwo ju lọ, ti mo ta ko iyansipo Muhammadu Buhari funpo aarẹ lọdun 2015. Mo sọ pe ajalu ati ewu lo maa mu ba Naijiria. Ko si eebu ti wọn o bu mi tan, ko si ọrọ alufanṣa ti wọn o sọ si mi tan tori ẹ, ṣugbọn lonii, gbogbo yin ti waa ri idi ti mo fi ta ko Buhari nigba naa. Ṣe ẹ ti waa ri i pe ina ti jo dori koko bayii. Ojoojumọ lọrọ ti mo sọ nigba naa n ja jo wa loju.”
Gomina ana fun ipinlẹ Ekiti, Peter Ayọdele Fayoṣe, lo sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi lede lori ikanni abẹyẹfo (tuita) rẹ laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii.
Fayoṣe bẹnu atẹ lu bi ipaya ati ifẹmiṣofo ṣe n fojoojumọ waye lai dawọ duro, paapaa niha Oke-Ọya ilẹ wa.
Fayoṣe tun sọ pe: “Mo lero pe gbogbo awọn ti Buhari bẹ lọwẹ lodi si mi, ati awọn ti wọn ṣatilẹyin fun un lati depo aarẹ nigba naa n gbadun biluu ṣe ri bayii, wọn gbọdọ maa pọnula si ijọba ẹ yii ni.
“Ohun to ṣe pataki ni pe ki gbogbo wa mọ iyatọ laarin ayipada rere yatọ si ti ẹtan. Ayipada ti wọn ṣeleri lati mu wa nigba yẹn, bo ṣe ri la jọ n wo yii.”
Ṣaaju lọkunrin naa ti sọ pe oun maa jade dupo aarẹ lọdun 2023, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, (PDP).