Itan igbesi aye Alaafin Adeyẹmi

Yẹmi Adedeji

Nibi ti ilu Ọyọ wa loni-in yii kọ lo wa tẹlẹ, Ọyọ meji ti wa tẹlẹ ki wọn too de ibi ti wọn wa loni-in yii. Agọdọyọ nibi ti wọn wa loni-in yii n jẹ tẹlẹ, nitori Agọ ni wọn n pe ilu naa tẹlẹ, Agọ-Ọja ni. Ọyọ akọkọ ti wa nitosi Odo Ọya, ko jinna si ọdọ awọn Tapa, nipinlẹ Niger, loni-in yii. Ogun lo le wọn nibẹ, ogun naa si le debii pe wọn ni lati sa wa si tosi nibi. Nigba naa ni wọn gunlẹ si Igboho, ti wọn si n jẹ Ọyọ Igboho. Ogun ko tun jẹ ki wọn le duro nibẹ naa pẹ titi, ibẹ ko si ṣee fi ṣe ibugbe ayeraye fun wọn. Ogun Eleduwe ni wọn ja gbẹyin ti nnkan fi de, ọrọ di igbẹ-aa-fẹwe, oko-la-a-wa-nnkan-ọbẹ, kaluku sa asala fun ẹmi wọn, ogun naa si tun tu ilu Ọyọ Igboho. Bẹẹ ni fun ọdun diẹ, awọn Ọyọ ko nibugbe ni ka pe e, wọn di ogunlende, wọn n sa kaakiri, nigba naa ni Olukuewu jẹwọ akọni, to si fun wọn ni Ọyọ tuntun.
Lasiko ti wọn fi n rin kiri yii, ti wọn n ti Ọyọ kan bọ si Ọyọ mi-in, awọn Alaafin mẹtalelọgbọn lo ti jẹ. Alaafin Ọranyan lo kọkọ jẹ, lẹyin naa ni Alaafin Ajuwọn Ajaka, Alaafin Ṣango Olufiran, Alaafin Aganju, Alaafin Oluaso, Alaafin Kọri, Alaafin Olugbogi, Alaafin Ofinran, Alaafin Egungunoju, Alaafin Ọrọmpọtọ, Alaafin Ajiboyede, Alaafin Abipa, Alaafin Ọbalokun Aganna-Erin, Alaafin Ajagbo, Alaafin Odarawu. Alaafin Kanran, Alaafin Jayin, Alaafin Ayibi, Alaafin Ọṣinyago, Alaafin Ojigi, Alaafin Gberu, Alaafin Amuniwaye, Alaafin Oniṣile, Alaafin Ọlabisi, Alaafin Awọnbioju, Alaafin Agboluaje, Alaafin Majẹogbe, Alaafin Abiọdun Adegoolu, Alaafin Aolẹ, Alaafin Adebọ, Alaafin Makuu, Alaafin Majo, Alaafin Amọdọ ati Alaafin Oluewu. Oluewu yii ni Alaafin to jẹ gbẹyin ni Ọyo atijọ, ọdun 1834 si 1837 lo fi jọba.

Ọkan ninu awọn ọmọọba Alaafin Abiọdun ni Atiba n ṣe, Atiba Olukuewu gan-an si lorukọ rẹ. Ọmọ ayaba kan to wa lati Akeitan ni. Itan sọ pe olododo gbaa ni ayaba yii, o si fẹran ọrẹ rẹ, ifẹ to ni si ọrẹ rẹ yii lo sọ ọ di ayaba. Awọn ọmọbinrin mejeeji yii jọ wa ni Gudugbu ni, nibi ti wọn ti n ṣe ọrẹ wọn. Lọjọ kan ni awọn ilari ki ọrẹ rẹ mọlẹ, ni wọn ba mu un, o di Ọyọ. Eyi ti wọn yoo gbọ ni pe wọn ti sọ ọrẹ rẹ di ayaba laafin, lẹyin to si ti jokoo sile loun nikan ti ko ri ọrẹ rẹ, o gbera pe oun n wa a lọ si aafin Ọyọ. Bẹẹ irin naa le nigba naa, sibẹ ọmọbinrin yii rin in, bo tilẹ jẹ pe wọn a maa ni ẹni to ba foju kan Alaafin ti ki i ṣe pe wọn ranṣẹ pe e ni, pipa ni wọn maa n pa a. Ṣugbọn obinrin yii loun ko ri eeyan ba sọrọ lati ọjọ ti wọn ti mu ọrẹ oun lọ, oun ko ni alajọsọ ọrọ mọ, gbigbe ile aye oun ko da nnkan kan, biku ba de ki oun kuku ku.
Nitori ẹ lo ṣe jẹ nigba to de ilu Ọyọ, ọna aafin lo mori le, awọn eeyan si n wo o, nitori wọn ti da a mọ pe ara oko kan ni, oko lo ti wa. Oun naa de aafin, o bẹrẹ si i ba awọn to ba ti ri ti wọn n jade laafin, tabi ti wọn fẹẹ wọle sinu aafin sọrọ pe oun n wa ọrẹ oun kan ni o, wọn ni ki lorukọ rẹ, o ni Ẹni-Olufọn ni. Ṣugbọn iyawo ati awọn agba obinrin ti pọ laafin ju ki ẹnikẹni da obinrin kekere ara igberiko kan mọ laarin awọn ayaba. Ko sẹni to mọ Ẹni-Olufọn, bẹẹ naa ni wọn si n sọ fun ọrẹ rẹ to n duro si ẹnu ọna aafin. Nigbẹyin, Alaafin Abiọdun gbọ pe ọmọbinrin kan ma ti igberiko wa to ni oun n wa ọkan ninu awọn iyawo ọba o. Ni ọba ba ni ki wọn pe e wa, nigba to si debẹ, o ni ko rojọ koun gbọ. Obinrin Wundia yii ni oun n wa ọrẹ oun ti oun gbọ pe iyawo ọba ni bayii, nitori lati kekere lawọn ti n ṣọrẹ bọ, oun ko si ni ẹlomi-in laye oun to jẹ alabaaro, ẹni kan toun ni niyi, ohun to jẹ ki oun wa a wa niyẹn.

Ẹnu ya ọba yii, o si beere pe ṣe ẹru ko ba a ni! Tabi ko mọ poun le ni ki wọn pa a tabi ki oun gbẹsẹ le e bi ayaba toun naa ko ni i le jade laafin mọ. Ọmọbinrin naa dahun pe to ba jẹ nitori ọrẹ oun ni o, bi ọrọ naa ba ja siku, oun ti fara mọ ọn, ṣugbọn to ba jẹ ti pe ki ọba gbẹsẹ le oun ni, ọrọ naa yoo dun mọ oun ninu ju, nitori iyẹn yoo jẹ ki oun maa ri ọrẹ oun lojoojumọ, awọn yoo si le jọ maa ṣe bi awọn ti n ṣe bọ. Bẹẹ ni ọba ni to ba ti jẹ oun to fẹ naa ree, oun gba a bii ayaba. Wọn pe ọrẹ rẹ fun un, wọn si jọ wa laafin titi ti ọmọbinrin yii fi loyun, nigba ti oyun rẹ si ga, Alaafin ni ko maa gbe e lọ si abule wọn, ki oun ati ọrẹ rẹ jọ maa lọ, ki wọn kuku maa ṣe aṣoju oun ni agbegbe wọn nibẹ, ki wọn mu ibẹ duro titi ti ọmọ oun yoo fi dagba. Ọmọ ti obinrin yii bi lo pada waa di Atiba, ẹni to tẹ ilu Ọyọ tuntun yii do.
Ki i ṣe pe Atiba tẹ ilu naa do bẹẹ, bi erin ti i dẹgbo ti i gba igbo lọwọ onigbo ni ọrọ naa ri, nitori nigba ti Atiba de Agọ-Ọja, ko i ti i jẹ ọba nigba naa, Ọmọọba ni, ṣugbọn ogun lo n le gbogbo wọn kiri. O ni oun yoo maa ba wọn gbe nibẹ, awọn ti wọn mọ ohun to le ti iru ibagbe bẹẹ jade ni ki Baalẹ Agọ-Ọja ma gba o, to ba gba, ohun ti yoo mu wahala wa fawọn lọjọ iwaju ni. Ṣugbọn baalẹ Agọ-Ọja ni nibo ni wọn ti n ṣe iyẹn, ṣebi ati oun, ati ilu oun, ati awọn ti wọn wa nibẹ, ṣe bi Alaafin lo ni gbogbo awọn, ko si agbara lọwọ oun lati ni ki ọmọ Ọba Atiba ma jokoo tawọn o. Bẹẹ ni Atiba jokoo, to si n tibẹ ja gbogbo ogun to n ja, to n tibẹ paṣẹ gbogbo. Lati ilẹ, eeyan lile kan ni Atiba n ṣe, onijakadi, oniwahala, ati ọkunrin kakaaka kan bayii ni. Ṣugbọn ohun to laye nigba naa ni, nitori asiko ogun ni.

Ki Atiba too de Agọ-Ọja, awọn Ilọrin lo n paṣẹ le ilu naa lori, wọn si ni Ajẹlẹ tiwọn nibẹ, ko si si ohun ti awọn ara Agọ-Ọja yoo ṣe lẹyin aṣẹ to ba wa lati Ilọrin. Nidii eyi, ko si ọmọ ti wọn bi nigba naa ti awọn Janmọọ ti wọn n paṣẹ Agọ-Ọja ko ni i fi tipatipa sọ lorukọ Musulumi, wọn ko gbọdọ jẹ orukọ mi-in mọ, bẹẹ ni wọn ko jẹ ki wọn sin ẹsin wọn gbogbo ni gbangba. Ibinu eyi wa lara ohun ti Atiba fi doju ija kọ gbogbo ohun to n jẹ ti Ilọrin. Bi ko ba wa wọn nija, awọn naa yoo wa a nija, nitori wọn ko fẹ ki Agọ-Ọja bọ sọwọ wọn, oun naa ko si fẹ ki wọn maa pe ibi ti oun ba wa ni ilu to wa labẹ Ilọrin, nigba to jẹ abẹ Ọyọ ni Ilọrin wa tẹlẹ, ayipada de ti esuru waa pajuda, to n le aja, nigba ti aye n jẹ aye, ko si bi Ilọrin yoo ṣe duro niwaju Ọyọ, nitori oko abẹ Ọyo ni i ṣe.
Ṣugbọn wọn pẹlu awọn ti wọn le Atiba funra ẹ de Agọ-Ọja, nigba to jẹ ogun Ilọrin yii lo fọ Ọyọ ile funra ẹ. Agọ Ọja yii lo waa di oju ija gan-an fun awọn ọmọ ogun Ilọrin ati awọn ọmọ ogun Yoruba to ku ti wọn wa lẹyin Ọyọ, ija naa si le. Bẹẹ Atiba ko ti i di Alaafin, ọmọọba lasan ṣi ni. Lẹnu fa-a-ki-n-fa-a yii ni Alaafin Oluewu waja si, bo si ti waja, ko si ṣiṣe ko si aiṣe, wọn fi Atiba Olukuewu jọba, nigba to ṣe pe ninu gbogbo awọn ọmọọba igba naa, ko tun si ẹni kan to lokiki tabi to lagbara to ju tirẹ lọ. Bo ti jọba lo yi nnkan pada biri, o sọ Oluyọle Ibadan di Ibaṣọrun, ki Oluyọle le maa lo awọn ọmọ ogun rẹ fun atilẹyin Ọyọ, ko si maa jagun foun gẹgẹ bii Alaafin. Bẹẹ naa lo fi Kurunmi Ijaye jẹ Aarẹ Ọna kakanfo, o ni ki oun naa wa lapa ọtun oun ko le maa jagun foun. Bayii ni Atiba fi Agọ-Ọja ṣe ibujokoo rẹ, ti wọn ko si pe e ni Agọ-Ọja mọ, to di Agọd’Ọyọ, to si ṣe bii ere bii ere di Ọyọ Alaafin.

Atiba jọba o, o si mu oriṣiriṣii nnkan meremere de si Ọyọ, atunṣe rẹpẹtẹ si ba a. Ogun pọ, ṣugbọn o fẹrẹ jẹ gbogbo ẹ naa ni wọn n bori. Yoo wa ninu itan titi aye pe lasiko Alaafin Atiba yii ni Yoruba bọ lọwọ awọn Fulani, nigba ti awọn ogun ọmọ Yoruba da wọn pada niluu Oṣogbo. Boya awọn ẹẹmaya ni wọn iba kun ilẹ Yoruba bayii bii ọba, nitori ohun ti wọn ṣe niluu Ilọrin lawọn Fulani naa fẹẹ ṣe ni ilẹ Yoruba yikayika. Ṣugbọn awọn ọmọ ogun Yoruba, labẹ Alaafin Atiba ti i ṣe Alaafin dide, wọn si ja ija naa titi ti wọn fi le awọn Fulani yii lọ. Nnkan pataki ni eleyii fun Yoruba, kaluku si n sọ lati igba naa pe aye Atiba lo ṣẹlẹ, Atiba lo ko Yoruba yọ lọwọ ewu Fulani, nitori oun lo fi Oluyọle jẹ Ibaṣọrun Ibadan, ogun Ibadan lo si le awọn Fulani wọnyi lọ. Lati igba naa, wọn ko si delẹ Yoruba mọ.
Asiko ti awọn oyinbo ṣẹṣẹ n da ẹsẹ wọ ibi to pada waa di Naijiria yii ni Atiba waja, ọdun 1859 lọba naa tẹri-gbaṣọ. Nigba ti Atiba ku yii, ki i ṣe pe ogun ti i tan naa, ṣugbọn o ti yatọ pupọ si ti atijọ, Ọyọ si ti fẹsẹ mulẹ nibi ti wọn jokoo si yii, ko sẹni to le pe ibẹ ni orukọ mi-in ju ilu Ọyọ lọ. Ọyọ tuntun tabi Ọyọ igbalode, nibẹ ni Ọyọ naa si wa titi doni yii. Atiba dagba daadaa ko too ku, ninu awọn ọba ti wọn n jẹ lasiko naa, ọkan loun, nitori ọpọ awọn Alaafin igba naa, paapaa awọn ti wọn jẹ lasiko ogun ati aṣikiri yii ki i pẹ rara. Ko sẹni ti yoo tete gbagbe Makuu to fi oṣu meji pere jẹ Alaafin. Ṣugbọn oun pẹ, o si bi awọn ọmọ rẹpẹtẹ ki iku too pa a. Nigba ti Atiba yoo fi waja, ẹni to ku ni akọbi fun un ni Adelu, oun naa ni wọn si fi jẹ Alaafin lẹyin rẹ. Ni 1859 ti baba rẹ papoda naa lo jọba, o si wa nibẹ titi di ọdun 1875.

Nigba ti Adelu waja ni 1875, ọkan ninu awọn ọmọ Atiba mi-in ni wọn tun fi jọba, orukọ rẹ si ni Alaafin Adeyẹmi, ẹni ti wọn n pe ni Alowolodu, tabi Alawolodu-bii-iyere. Ọmọ kẹrin Alaafin Atiba ni Adeyẹmi i ṣe. Adeṣiyan ni iba jẹ Alaafin igba naa, nitori oun lẹgbọn, ṣugbọn funra rẹ lo ni ki Adeyẹmi lọọ jọba naa nitori agbara toun ko gbe e mọ, aiya ara wa foun. O sọ fun awọn ti wọn fẹẹ fi i jẹ Alaafin pe wahala ifinijoye Alaafin pọ to bẹẹ gẹẹ debii pe ti oun ba ni ki oun gba a, bo tilẹ jẹ ki oun de ade naa fun ọjọ kan pere, iyọnu ni yoo jẹ foun ati awọn to fẹẹ fi oun joye, ati gbogbo ilu lapapọ. Nitori bẹẹ, o ni ki awọn ijoye ma daamu ara wọn jinna, nigba ti Ọlọrun ti ṣe e ti aburo oun wa, iyẹn Adeyẹmi, oun fi gbogbo ara mọ ọn pe ko gbade naa, ki wọn si sọ ọ di Alaafin.
Ko si ẹni kan bayii to lodi si i pe ki Adeyẹmi di Alaafin laarin ilu, afi ọkan ninu awọn ọmọ ọmọ baba rẹ. Ṣebi Adelu lo jẹ Alaafin to waja, ọmọ toun naa ti wọn n pe ni Lawani ni ko si ohun to ṣe oun ti oun naa ko le jẹ ẹ. Kekere ni wọn p’ọrọ yii, wọn ni ko ma ba a du u, nitori nigba ti aburo baba rẹ ti wọn jọ jẹ ọmọ baba kan naa ba ṣi wa laye, p’oun ti oun jẹ ọmọ ọmọ ko le jẹ ẹ. Ṣugbọn Lawani ko gba, o ni ki wọn jẹ ki awọn jọ du u, bi ko ba ja mọ oun lọwọ, ohunkohun to ba tidi ẹ yọ, oun fara mọ ọn. Bẹẹ lo ṣe jẹ pe Lawani du oye naa pẹlu aburo baba rẹ, ṣugbọn awọn Ọyọmesi ti mọ ohun ti wọn yoo ṣe ati ẹni ti wọn yoo mu, ko si ṣoro fun wọn lati mu Adeyẹmi pe oun lawọn fẹ nipo ọba. Bi ọrọ ba si ti da bayii, ko si ohun ti Lawani le ṣe, yoo fi Ọyọ silẹ fun Alaafin ti wọn ba mu ni, bẹẹ naa lo si ṣe ṣe.

Yatọ si eyi, ko tun si araalu kan tabi ọmọọba mi-in to lodi si Adeyẹmi nitori gbajumọ ni, ọpọ eeyan lo mọ ọn tẹlẹ, olowo ni. Awọn oniṣowo gbogbo to n lọ lati Ibadan, Abẹokuta ati Ijẹbu, ile rẹ ni wọn maa n de si, ti yoo si ṣe gbogbo wọn lalejo bamubamu titi ti wọn yoo fi lọ. Nigba to wa lọmọ ọba si ree, oun ati awọn ero ni yoo jọ lọ si ọdọ awọn ti wọn n ṣe ọti, ti kaluku yoo si mu un tẹ ara rẹ lọrun. Eyi lo ṣe jẹ ko sibi ti ẹ ri i ti ẹ ko ni i ri ero lẹyin rẹ, bo ṣe niluu Ọyọ ni o, bo si jẹ lẹyin odi, gbajugbaja ọkunrin ni. Nitori ẹ ni ọkan gbogbo ilu ṣe balẹ pe to ba jẹ oun ni yoo di Alaafin, ko le si wahala, nitori atọbatẹlẹ loun ko too jọba. Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ nigba to jọba tan, nitori iṣẹlẹ kan ṣẹ lasiko to n jọba ti awọn araalu fi mọ pe asiko tirẹ yoo le diẹ, ogun oriṣiriṣii ni yoo ja ilu wọn. Lati Ile-lfẹ lo ti han wa pe igba rẹ yoo le diẹ o jare.
Igba Iwa meji ni wọn gbe fun un, awọn igba yii naa ni wọn si fi n mọ bi asiko Alaafin kọọkan yoo ṣe ri. Ninu awọn igba meji yii, ọkan wa ti wọn yoo ko owo, aṣọ, ilẹkẹ, ati awọn nnkan daadaa mi-in si ninu, ekeji yoo si kun fun nnkan ija bii ẹtu ibọn, bileedi, ọta-ibọn, ida kekere, ọbẹ, ọfa ati ọrun kekere, ati awọn nnkan mi-in ti wọn fi n jagun. Nigba ti wọn ko igba mejeeji de iwaju Alaafin Adeyẹmi, to si jẹ bakan naa ni awọn igba mejeeji ṣe ri ti ẹni kan ko le mọ iyatọ, eyi to fi ọwọ ara rẹ gbe bayii, igba ogun ni. Nigba ti awọn eletutu ri i, niṣe ni wọn kọ haa, wọn ti mọ pe ogun yoo pọ lasiko ọba tuntun naa. Bẹẹ lo si ri, nitori ni asiko Adeyẹmi yii ni ogun ti Yoruba fi ọdun mẹrindinlogun ja bẹrẹ, iyẹn ogun Kiriji. Oju ẹ lo bẹrẹ, oju ẹ lo si pari. Asiko rẹ ni awọn oyinbo gba Ọyọ, ti wọn fi ajẹlẹ si i, afi bii igba ti Ọyọ bọ lọwọ Alaafin.

Ṣugbọn ti a ba ti yọwọ ogun ti wọn n ja kaakir ilẹ Yoruba naa, ilu Ọyọ funra rẹ ni isinmi, idagbasoke si wọle wa. Ọdun 1905 ni Alaafin Adeyẹmi waja, nigba naa ni wọn si pe Lawani Agogo-Ija, ẹni to ba Adeyẹmi du oye naa nijọsi pe ko maa bọ lati Ibadan to wa, ko waa jẹ Alaafin. Bayii ni Lawani di Alaafin ni 1905, oun si ni ọrẹ oyinbo akọkọ, nitori oun ati Captain Ross ti wọn ti jọ wa n’Ibadan mọ ọwọ ara wọn. Ṣugbọn Alaafin Lawani ko pẹ rara lori oye, ọdun 1911 ni ọba naa waja, ọrọ naa si dun gbogbo ilu. Ohun to jẹ ki wọn gba lati fi akọbi rẹ, Ṣiyanbọla Onikẹpọ Ladigbolu jẹ Alaafin ree, aye rẹ si dara, nitori oun gangan lọrẹ oyinbo, baba rẹ kan n ba oyinbo ṣe nitori agbara oyinbo igba naa ni. Ṣugbọn ni ti Ṣiyanbọla Onikẹẹpọ, ọrẹ gidi loun ati Captain Ross.
Asiko Ladigbolu akọkọ yii ni wọn da agbara gbogbo pada fun Ọyọ, ti Ọyọ si pada di alagbara lori Ibadan, nitori ko too di igba naa, ofin awọn oyinbo ti gbe Ibadan kari Ọyọ, Ṣiyanbọla Ladigbolu lo da kinni naa pada fun wọn. Nitori o pẹ lori oye, o lo odidi ọdun mẹtalelọgbon, ohun nla nla lo mu wọ ilu Ọyọ wa, ko si si ẹni to ranti Ọyọ ti ko ranti Ṣiyanbọla Ladigbolu to jẹ Alaafin. Ni 1944, ọba naa waja, wọn si fi Adeniran Adeyẹmi jẹ lọdun 1945. Adeniran ti wọn fi jẹ ọba yii, oun ni Arẹmọ, iyẹn akọbi Adelakun, Adelakun ti i ṣe ọmọ Alaafin Adeyẹmi akọkọ. Adeyẹmi Keji yii ko pẹ lori oye, ija waye laarin oun ati awọn oloṣelu igba naa, wọn si yọ ọ nipo ọba lọdun 1956. Lẹyin ti wọn yọ ọ, Bello Gbadegẹṣin, ọmọ Ladigbolu, mi-in jọba, oun ni Ladigbolu Keji, ni 1956 yii naa ni. Ṣugbọn oun naa ko pẹ, ọdun mejila lo ṣe. O waja ni 1968.

Nigba naa ni ipo ọba tun ṣi silẹ, awọn Ọyọmesi si jokoo, wọn fori kori, wọn ni ki wọn fi Lamidi Ọlayiwọla, ọmọ Adeyẹmi mi-in jẹ Alaafin. Njẹ ta ni Lamidi Ọlayiwọla ti wọn fẹẹ fi jẹ Alaafin yii ni 1968? E pade wa lọsẹ to n bọ.

Leave a Reply