Ẹran ẹtu ni mo ri lọọọkan ti mo fi yinbọn, afigba ti mo ri oku Baba Imaamu nilẹ-Sulaiman

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọkunrin kan to jẹ ọdẹ (hunter) labule Alaguntan, niluu Orilẹ-Owu, nipinlẹ Ọṣun, Sulaiman Jimoh, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, lo ti n ka boroboro nileeṣẹ ọlọpaa lori ẹsun ipaniyan.

Gẹgẹ bi Alukoro funleeṣẹ ọlọpaa, SP Yẹmisi Ọpalọla, ṣe ṣalaye fun Alaroye, aago mọkanla aabọ aarọ ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Ọpalọla sọ pe ẹnikan lo lọọ fi to awọn ọlọpaa agbegbe naa leti pe Sulaiman yinbọn pa baba oun, Adegun Yusuf, ẹni ọdun mejidinlọgọrin ninu oko rẹ.
O ni awọn ọlọpaa ni wọn fi panpẹ ọba gbe Sulaiman, to si jẹwọ pe loootọ ni.
Sulaiman sọ pe lọjọ naa, ẹran ẹtu loun n wo lọọọkan ninu igbo ti oun fi yinbọn, o ni nigba ti oun debẹ loun ri i pe Baba Imaamu abule Alaguntan tan.
Ọpalọla sọ pe ni kete tiwadii ba ti pari ni afurasi naa yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply