Ti mo ba di aarẹ, iṣejọba mi yoo mu alaafia, iṣọkan ati idagbasoke ba ilẹ Naijiria-Ọṣinbajo

Gbenga Amos, Abẹokuta

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ṣeleri pe oun ati gbogbo eeyan ipinlẹ Ogun yoo ṣe atilẹyin fun erongba Igbakeji Aarẹ ilẹ wa to tun jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ogun, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, lati di aarẹ Naijiria.
Abiọdun sọrọ yii nibi ipade awọn alẹnulọrọ ti wọn ṣe ni aafin awọn ọba alaye kan nipinlẹ Ogun. O ni gbogbo atilẹyin to ba yẹ loun yoo fun Ọṣinbajo lati ri i pe o tẹsiwaju ninu awọn iṣẹ ti Aarẹ Muhammadu Buhari n ṣe.
Gomina ni laarin ọdun meje ti Ọṣinbajo fi wa nipo gẹgẹ bii Igbakeji Aarẹ, o ti ṣe atilẹyin fun awọn aṣeyọri tijọba Buhari ṣe lawọn agbọn kan, nidii eyi, o kun oju oṣuwọn daadaa lati dupo aarẹ ilẹ wa lọdun to n bọ.
Dapọ Abiọdun ni, ‘Wiwa Igbakeji Aarẹ wa sibi yii lonii, bii igba teeyan wa sile ni o, inu wa si dun si ipinnu yin lati dupo aarẹ. O kun oju oṣuwọn, o si ni gbogbo ohun to pe fun lati dari orileede yii lọ si ibi giga.
‘Gbogbo wa la mọ iduroṣinṣin rẹ, iwa ọmọluabi ti o ni, bẹẹ lo si ti sin orileede yii pẹlu iṣẹ takuntakun laarin ọdun meje. A ko si ṣiyemeji lọkan wa pe wa a ṣe daadaa ti o ba di aarẹ. Nidii eleyii, a maa ṣatilẹyin fun ọ.’
Nigba to n sọrọ nibẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ni oun ko wa si ipinlẹ naa lati polongo ibo, ṣugbọn lati fi erongba oun lati dupo aarẹ Naijiria han fun awọn eeyan oun.
Ọṣinbajo ni, ‘‘Ipo igbakeji Aarẹ jẹ anfaani lati sin awọn eeyan pẹlu otitọ inu to ga ju lọ. Gbogbo eleyii ni mo si fi sinu iṣẹ mi. Mo jẹ oludije ti yoo bẹrẹ iṣẹ loju-ẹsẹ ti wọn ba ti yan mi sipo aarẹ
‘‘Mo ni ọgbọn ati gbogbo amuyẹ to pe fun lati di ipo naa mu, ki n si ṣiṣẹ lori awọn ohun ti awọn mi-in ti gbe kalẹ. Iṣejọba mi yoo mu alaafia iṣọkan ati idagbasoke ba ilẹ Naijiria.
‘‘Mo ti kẹkọọ daadaa, ti wọn ba pe mi pe ki n waa dari orileede yii, ṣẹ ma a waa sọ pe rara ni? Mo ti ṣepinnu pe ma a dije dupo aarẹ, mo ti jẹjẹẹ nipa ijọba orileede Naijiria. O jẹ ẹjẹ fun awọn eeyan wa, awọn ọmọ wa, ati fun ọjọ iwaju Naijiria. Mi o jẹ ẹnikẹni mi-in ni iṣotitọ mi-in ju ẹjẹ eyi lọ.’’
Awọn ọba bii Akarigbo ilẹ Rẹmọ, Alake ilẹ Egba ni wọn fi atilẹyin wọn han si erongba Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo lati dupo aarẹ. Alake ni Ọṣinbajo ti ṣe gbogbo ohun to yẹ, o si kun oju oṣuwọn lati de ipo naa. Bakan naa ni Akarigbo Rẹmọ, Ọba Babatunde Ajayi, ni ọkunrin naa kun oju oṣuwọn lati dari orileede yii, pẹlu awọn ohun to gbe ṣe gẹgẹ bii aAdele Aarẹ nigba ti Buhari ko si nile.
Alake gbadura fun Ọṣinbajo pe nigba ti yoo ba fi pada wa si aafin yii, yoo wa gege bii aarẹ Naijiria, ti itẹsiwaju ti ko lẹgbẹ yoo si ba orileede wa lasiko iṣejọba rẹ.

Leave a Reply