Faith Adebọla
Olori orileede wa, Aarẹ Muhammadu Buhari, ti wa nipinlẹ Ebonyi lasiko yii, abẹwo ọlọjọ meji ni baba naa n ṣe si ipinlẹ ọhun.
Bo tilẹ jẹ pe awọn oṣiṣẹ rẹ ko ti i ṣalaye idi tọrọ fi ri bẹẹ fẹnikan titi di ba a ṣe n sọ yii, nnkan bii aago mẹwaa aabọ alẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ni baaluu Aarẹ balẹ si ipinlẹ Enugu, ni papakọ ofurufu Akanu Ibiam, to wa nipinlẹ naa, dipo ti iba fi lọọ balẹ si ipinlẹ Ebonyi taarata.
Gomina ipinlẹ Enugu, Ifeanyi Ugwuayi, ati ekeji rẹ lati ipinlẹ Ebonyi, David Umahi, lo waa ki Buhari kaabọ bo ṣe n sọkalẹ ni papakọ ofurufu naa, lẹyin eyi ni oun ati olugbalejo rẹ, Umahi, tẹkọ leti lọ si ipinlẹ Enugu.
Ohun ta a gbọ ni pe Aarẹ Buhari yoo lo anfaani abẹwo ọhun lati ṣi awọn iṣẹ akanṣe kan ti Gomina Umahi ti pari rẹ, yoo si tun ṣepade pẹlu awọn alẹnulọrọ ati awọn agbaagba iha Guusu/Ila-Oorun ilẹ wa, iyẹn ilẹ Yibo, ko too pada silu Abuja.
Bi wọn o tilẹ fi pato ohun ti ijiroro wọn yoo da lori lede, ireti wa pe ọrọ eto aabo agbegbe naa to n fojoojumọ buru si i, ati itajẹsilẹ to n waye lemọlemọ, titi kan ọrọ oṣelu, yoo gba iwaju ninu ifikunlukun wọn.
Bakan naa lawọn eeyan reti pe wọn yoo lo anfaani abẹwo yii lati ba Buhari sọrọ lori bi gbajugbaja ajijangbara ilẹ Ibo nni, Ọgbẹni Nnamdi Kanu, to wa lahaamọ awọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, yoo ṣe dẹni ominira.