Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ibẹru ati ipaya ti bo ọkan awọn eeyan ipinlẹ Ekiti pẹlu bi awọn ajinigbe kan ti wọn ko ti i mọ ṣe ji eeyan mẹrin gbe ni Oke-Ako, loju ọna Irele to wa ni ijọba ibilẹ Ikọle, nipinlẹ Ekiti.
Gẹgẹ bi awọn eeyan agbegbe naa to ba awọn akọroyin sọrọ ni Ado-Ekiti ṣe sọ, wọn ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni deede aago meje aabọ alẹ Ọjọbọ, Tọsidee. Awọn ajinigbe naa si ti ranṣẹ si awọn mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe naa pe wọn gbọdọ san ogun miliọnu naira gẹgẹ bii owo itusilẹ wọn.
Awọn ti wọn ji gbe naa jẹ dẹrẹba ati ero ọkọ akero kekere kan to n lọ lati ipinlẹ Ekiti si ipinlẹ Kogi. Loju ọna naa ni awọn ajinigbe ti da ọkọ naa duro ni ibi kan to ni koto ni oju popo.
Wọn ṣalaye pe dẹrẹba ọkọ naa to jẹ ọmọ bibi ilu Ipaọ-Ekiti, ni wọn ko wọ inu igbo kan, lẹyin ti wọn ti kọkọ ko eeyan meji ninu ọkọ miiran to n ko eedu loju ọna naa.
Ẹnikan to n gbe ni Oke-Ako, ti ọrọ naa ṣoju rẹ ṣalaye pe awọn wa ni ipade kan ni deede aago mẹjọ alẹ ọjọ Wẹsidee, nigba ti awọn sadeede gbọ pe wọn fi ọkọ meji kan silẹ si oju ọna, ti wọn si ṣilẹkun wọn kalẹ laarin ọna naa, ti ko si si ẹnikankan ninu ọkọ mejeeji ọhun.
O ṣalaye pe bi awọn ṣe de idi ọkọ naa lawọn ri i pe wọn ti ji awọn ero wọn gbe. O fi kun un pe awọn ajinigbe naa ti pe lati beere ogun miliọnu Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ.
Ọkunrin yii ni nigba tawọn ajinigbe naa n ba awọn araalu sọrọ lawọn ṣẹṣẹ mọ pe eeyan mẹrin, dẹrẹba meji ati awọn ero ọkọ meji, ti wọn wọ ọkọ lati Irele-Ekiti, ti wọn n lọ si Ayedun-Ekiti, ni wọn ji ko.
Ọkan lara awọn dẹrẹba ọkọ naa ṣalaye pe oun ko mọ ibikan pato ti awọn wa ninu igbo naa, ṣugbọn odo nla kan ko jinna sibi ti awọn wa, tawọn si n gbọ iro omi naa bo ṣe n ho.
A gbọ pe awọn ọlọpaa ati ẹṣọ Amọtẹkun, pẹlu awọn ọdẹ ibilẹ ti wa ninu igbo ni agbegbe naa, ti wọn si n ṣiṣẹ takuntakun lati gba awọn ti wọn ji ko naa silẹ.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro fun awọn ilu Ẹkamẹfa, Ọgbẹni Oluwafẹmi Abayọmi, sọ pe ọrọ aabo lo jẹ iṣoro kan pataki to n dojukọ awọn eeyan agbegbe naa.
O ṣalaye pe awọn to n gbe ni ilu mẹfẹẹfa naa ko le jade tabi ki wọn inu oko wọn.
O pe ijọba apapọ pe ki wọn ran awọn eeyan agbegbe naa lọwọ, o ṣalaye pe awọn ṣọja wa loju ọna ni Ipaọ ati Oke-Ako, ṣugbọn iṣẹlẹ ijinigbe ko tori eyi dawọ duro.