Adajọ ni ki wọn yẹgi fun Quareem to pa fijilante mẹrin ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu 

Ile-ẹjọ giga kan to fi ilu Ilọrin ṣe ibujokoo, ti pasẹ pe ki wọn yẹgi fun ọdaran kan, Quareem Ibrahim, fẹsun pe o ṣeku pa fijilante mẹrin ni Kaiama, nijọba ibilẹ Kaiama, nipinlẹ Kwara, lọdun 2018.

Tẹ o ba gbagbe, lọdun 2018 ni wọn mu Quareem Ibrahim ati awọn afurasi mọkandinlogun miiran fẹsun pe wọn ṣeku pa awọn fijilante mẹrin niluu Kaiama, nipinlẹ Kwara, ti igbẹjọ si ti bẹrẹ lati igba naa, awọn ẹlẹrii mẹjọ ni wọn jẹrii nile-ẹjọ pe Quareem, lo ṣeku pa awọn fijilante to doloogbe ọhun.

Awọn ẹlẹrii mẹjọ ti agbefọba ko lọ si ile-ẹjọ ko awọn ẹri siwaju adajọ to ṣafihan pe Quareem jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an. Ọdaran naa gba pe oun jẹbi ẹsun naa. Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan an ni ipaniyan, gbigbe ohun ija oloro kiri lọna aitọ, idigunjale ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Nigba ti Adajọ Adenikẹ Akinpẹlu gbe idajọ rẹ kalẹ, o ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii ati awọn ẹri ti wọn ko siwaju ile-ẹjọ, awọn mọkandinlogun to ku ko mọwọ-mẹsẹ ninu iku awọn oloogbe, fun idi eyi, o ni ki wọn maa lọ sile layọ ati alaafia, o ni Quareem Ibrahim jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, ki wọn lọọ yẹgi fun un, ko si tun sẹwọn ọdun mẹwaa fun ẹsun gbigbe ohun ija oloro kiri lọna aitọ.

Leave a Reply