Ọdun Ileya: Ijọba kede ọjọ Aje ati Iṣẹgun fun isinmi lẹnu iṣẹ

Faith Adebọla

Latari pọpọ ṣinṣin ọdun Ileya, Eid-el-Kabir, to gbode, ijọba apapọ ti kede ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun yii, ati ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, to tẹle e gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.

Minisita fun ọrọ abẹle, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, to fi ikede yii lede l’Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, sọ pe ijọba apapọ ki awọn Musulumi jake-jado orileede yii ati lẹyin odi ku oriire ti ọdun pataki ti wọn ti n foju sọna fun yii.

O gba awọn Musulumi lati lo anfaani yii lati fi ifẹ, alaafia, aanu, ifara-ẹni-rubọ, ati ifẹ ọmọlakeji han gẹgẹ bi Anọbi Muhammad ṣe fi apẹẹrẹ lelẹ fun wọn, bẹẹ lo gba wọn niyanju lati lo asiko naa fun adura, ki iṣọkan, aabo ati idẹra, le jọba lorileedee Naijiria.

Arẹgbẹṣọla ni, “Iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari ni in lọkan, ko si ni in jawọ ninu ilakaka rẹ lati pese aabo to peye fun ẹmi ati dukia awọn ọmọ Naijiria, ironi-lagbara fun araalu, ati ipese awọn ohun amayedẹrun, titi kan ipese aabo lawọn ileewe wa.”

Minisita naa waa ṣekilọ fawọn eeyan lati wa lojufo, paapaa lasiko pọpọ ṣinṣin ọdun ti awọn olubi ẹda le fẹẹ lo anfaani ikorajọ awọn ero ti yoo waye lọpọ ilu, o ni oju lalakan fi n ṣọri, ki wọn wa lojufo si irin tabi irisi ẹnikẹni to ba mu ifura dani, ki wọn si tete kan si awọn agbofinro ti wọn ba ti ri ohunkohun to kọ wọn lominu.

O ṣadura pe ọdun ayọ lawọn eeyan yoo ṣe.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹsan-an, oṣu Keje, ọdun yii, ni ajọdun Ileya yoo waye. Pẹlu ikede yii, tawọn oṣiṣẹ ba ti bẹrẹ isinmi opin ọsẹ nirọlẹ ọjọ Satide, o di owurọ ọjọ Wẹsidee ki wọn too pada ṣenu iṣẹ.

Leave a Reply