Wọn ti mu Adetunji ati Ọpẹyẹmi to ji ẹran Ileya Sọdiq gbe l’Ogijo

Gbenga Amos, Abẹokuta

Bi ko ba jẹ pe o taji loju oorun nigba to n gbọ kurukẹrẹ kan loju windo rẹ, ninu ọgba to so ẹran Ileya rẹ mọ, ọbẹ iba se’lẹ fun Ọgbẹni Sọdiq Abọlọrẹ, niluu Ogijo, nipinlẹ Ogun, tori diẹ lo ku ki Ọpẹyẹmi Ogunlokun ati Adetunji Alagbe ji ẹran naa gbe, sa lọ, ki ọwọ too ba wọn.

Iṣẹlẹ yii waye ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Keje yii, nigba to ku ọjọ mẹta pere ti wọn yoo fi ẹran naa ṣe ọdun Ileya.

Gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ṣe ṣalaye ninu atẹjade kan to fi lede, o ni nnkan bii aago mẹta oru ọjọ naa ni Sọdiq sọ p’oun bẹrẹ si i gbọ ariwo to ṣajeji nibi toun so ẹran Ileya oun mọ. Nigba toun si dọgbọn yọju loju windo lati wo ohun to fa a, oun ri i pe wọn ti ti irin geeti to wa nibi toun so ẹran mọ lulẹ, oun si ri firifiri awọn eeyan meji kan ti wọn n fa ẹran Ileya toun ra ni ẹgbẹrun lọna ọgọfa Naira (N120,000), lọ.

Kia lọkunrin naa loun wọ ṣokoto oun, toun si jade sita loru ọhun, ṣugbọn nigba ti yoo fi jade, awọn ole yii ti n gbe ẹran naa sinu buutu ọkọ ayọkẹlẹ kan ti wọn gbe wa, dẹrẹba kan si wa ninu ọkọ naa to n peṣẹ fun wọn pe ki wọn ṣe kia.

Nigba ti Sodiq ko mọ ohun to le ṣe mọ, niṣe lo fiboosi bọnu laajin oru naa, to kigbe sawọn aladuugbo lati jade, awọn ole ti waa ji ẹran gbe, eyi lo mu kawọn gende kan sare jade.

Awọn ole naa gbiyanju lati sa lọ, ṣugbọn wọn le wọn mu, ọwọ si ba Ọpẹyẹmi ati Adetunji, dẹrẹba ọkọ naa sa lọ pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn gbe wa, ṣugbọn wọn ko ri ẹran naa gbe lọ.

Lẹyin ti wọn ti din dundu iya fun wọn, awọn eeyan naa ke sawọn ọlọpaa teṣan Ogijo, awọn ọlọpaa si waa mu wọn.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ki wọn taari awọn afurasi ọdaran mejeeji sọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ to n wadii ẹsun idigunjale, ki wọn le ṣe iwadii to lọọrin lori iṣẹlẹ ọhun, ki ọrọ to di tile-ẹjọ.

Leave a Reply