Nibi ti obinrin yii ti fẹẹ ji ọmọ gbe lọwọ ti tẹ ẹ n’Ikarẹ Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Diẹ lo ku ki wọn dana sun obinrin ajọmọgbe kan tọwọ tẹ n’Ikarẹ Akoko, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ ta a wa yii.

ALAROYE gbọ pe obinrin ọhun to kọ lati darukọ ara rẹ ni wọn mu pẹlu ọmọ ọdun kan aabọ to fẹẹ ji gbe lagbegbe Semusemu, niluu Ikarẹ.

Ajọmọgbe ọhun ni wọn lo ki ọmọdekunrin naa mọlẹ nigba to ṣakiyesi pe iya rẹ ko si nitosi, bo ṣe gbe ọmọ ọlọmọ pọn tan lo tẹsẹ mọrin, to si n gbiyanju ati tete kuro lagbegbe naa laimọ pe ẹnikan n wo gbogbo itu ti oun n pa.

Bi araadugbo to ri gbọmọgbọmọ ọhun ṣe figbe bọnu lati pe akiyesi awọn eeyan si ohun to n ṣẹlẹ ni wọn lobinrin naa fere ge e, to si n sa lọ pẹlu ọmọ ọlọmọ lẹyin rẹ.

Lẹyin tọwọ pada tẹ ẹ ti wọn si n yẹ ara rẹ wo ni wọn ka foonu olowo nla kan mọ ọn lọwọ pẹlu ọpọlọpọ ipe ti ko ti i raaye gbe lori ẹrọ ibanisọrọ ọhun.

Awọn agbaagba kan ni wọn fọgbọn gba a silẹ lọwọ awọn ti wọn fẹẹ dana sun un lọjọ naa ti wọn si fa a le awọn ọlọpaa tesan Ikarẹ lọwọ.

Leave a Reply