Baba ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta dawati l’Ogbomọṣọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Inu ipayinkeke nidile Arẹo, niluu Ogbomọṣọ, wa bayii pẹlu bi ọkan ninu wọn, Oluṣẹgun Abayọmi Arẹo, to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta (46) ṣe dawati.

O ti n lọ bii ọsẹ meji bayii ti ẹbi, ara ati ojulumọ kankan ti fi oju kan ọkunrin naa gbẹyin. Lati ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii, gan-an lo ti jade ti ko dari wọle mọ.

Wọn ni birikila niṣẹ Ọgbẹni Oluṣẹgun, ṣugbọn a maa fi alupupu to ni ṣiṣẹ ọkada nigba mi-in ti owo ba fẹẹ safẹẹrẹ si i lọwọ.

Iṣẹ ọkada naa ni wọn lo ṣe lọ lọjọ Satide ọhun to fi dẹni ti ẹnikan ko ti i foju kan latọjọ naa titi ta a fi pari iroyin yii.

Aburo ọkunrin birikila yii, Ọgbẹni Ọladimeji, ṣalaye pe “ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ yẹn ni wọn jade nile. Wọn ba awọn ọlọkada yuniiti ọsibitu LAUTECH (niluu Ogbomọṣọ) ṣepade, nitori ibi ti wọn maa n fi ọkada na niyẹn.

“Ni kete ti wọn pari ipade ni wọn ṣiṣẹ ọkada diẹ nitori wọn ko ri ibi iṣẹ birikila lọ lọjọ yẹn. Awọn ati iyawo wọn sọrọ ko too di pe wọn bẹrẹ si i  gbe ero kaakiri. Ṣugbọn nigba to di nnkan bii aago mẹta ọsan niyawo wọn n gbiyanju lati pe wọn, ṣugbọn ko ri wọn pe mọ, nitori aago wọn ko lo lọ mọ, bo tilẹ jẹ pe o ti pe wọn sori foonu ti wọn si ti jọ sọrọ fun bii ẹẹmeloo kan tẹlẹ.

“Iyawo wọn lọọ ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun Ọgbẹni Ọlọgbin, alaga ẹgbẹ awọn lanlọọdu adugbo wọn. Awọn yẹn ni wọn lọ si teṣan ọlọpaa lati fi iṣẹlẹ yẹn to wọn leti.

Gbogbo wa yii naa la dara pọ mọ awọn ọlọpaa nigba ti wọn n wa wọn kaakiri. Gbogbo ọsibitu ta a mọ la lọọ yẹwo, pe boya wọn lasidẹnti ni, ṣugbọn a ko ri wọn ni gbogbo ibi ta a wa wọn lọ.”

Iyawo kan ati ọmọ mẹta l’Ọgbẹni Ọladimeji fi sile to fi dẹni to jade ti ko dari pada sile mọ

Awọn ẹbi ọkunrin naa ti waa rọ ẹnikẹni to ba ri i tabi gburoo ẹ lati kan si agọ ọlọpaa to ba sun mọ wọn tabi ki wọn pe ọkan ninu awọn nọmba ibanisọrọ wọnyi: 07062030077 ati 08038031627.

 

Leave a Reply