Miliọnu marun-un lawọn agbebọn to ji Saheed n’Ilọrin n beere fun 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn ajinigbe to ji Mallam Saheed Taiwo Olowududu gbe ni iwaju ile rẹ lagbegbe Okoolowo, lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ti n beere fun miliọnu marun-un Naira owo itusilẹ lọwọ mọlẹbi rẹ.

Ọkan lara mọlẹbi rẹ to ba ALAROYE sọrọ sọ pe alẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu to kọja, ni awọn ajinigbe naa ya bo agbegbe ile awọn Rasheed, Lokoolowo, ti wọn si gbe sa lọ.

Agboole  Olowududu,  lagbegbe Alore, niluu Ilọrin, ni ile wọn, sugbọn to n gbe ni ile rẹ to kọ si agbegbe Okoolowo, ti wọn ti ji i gbe. ALAROYE gbọ pe wọn fẹẹ ṣe igbeyawo awọn aburo rẹ lẹyin ọdun ileya to n bọ yii.

Awọn agbebọn naa pe mọlẹ rẹ miliọnu marun-un Naira ni wọn n beere fun, awọn mọlẹbi ti sa miliọnu meji Naira jọ,  wọn gbe fun awọn ajinigbe, ṣugbọn wọn o tu Saheed silẹ titi di akoko ti a n ko iroyin yii jọ. Awọn mọlẹbi ti waa rọ gbogbo ọmọ Naijiria ki wọn fi adura ran Saheed lọwọ ko le kuro lakata awọn agbebọn naa layọ ati alaafia nitori ilera ara rẹ.

Leave a Reply