Wọn ni mo gbọdọ jo nihooho laarin abule tori mo yan ale, mi o le ṣe e, ẹ tu wa ka – Sandra

Faith Adebọla, Eko

Ẹnu ara ẹni la fi n kọ ‘mi o jẹ,’ ni iyaale ile kan, Sandra Iyenanye, sọ ọrọ da ni kootu kọkọ-kọkọ to wa niluu Igando, nipinlẹ Eko, nigba to rọ ile-ẹjọ naa lati fa iwe igbeyawo oun ati ọkọ rẹ, Festus Iyenanye, ya, ki wọn fopin si mareeji naa, tori loootọ loun yan ale nigba tọkọ oun ko si nile, ṣugbọn oun o le jo ijo ẹlẹya tawọn mọlẹbi ọkọ oun ni koun lọọ jo nihooho yika abule, o ni kaka ki oun ṣe iru nnkan bẹẹ, ki awọn pin gaari, oun fẹẹ pọ soke ra’ja.

Sandra, to n gbe l’Ojule kẹjọ, Opopona Jayeọba, niluu Igando, lo lọọ jawe fun ọkọ rẹ nile-ẹjọ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Keje yii, o ni igbeyawo naa ti su oun, tori alaiṣootọ lọkọ oun, o n yan ale, o n rẹ oun jẹ, o si tun pa oun bii aṣọ to gbo.

Ninu alaye rẹ, Sandra ni: “Lati ọdun 2010 ta a ti ṣegbeyawo, ọkọ mi to lọ si orileede Austria ti pa mi ti, ẹẹmẹrin si ẹẹmarun-un pere lo ti wale, o fi bẹliiti lu mi lẹẹkan nitori obinrin mi-in to n gbe kiri.

“Nigba ti mo fura pe o ti n yan obinrin mi-in l’ale lọdun 2010, mo ko o loju, ṣugbọn dipo ko ṣalaye tabi bẹ mi, niṣe lo fa bẹliiti yọ, to ko o bo mi, ni mo ba sa lọ sọdọ aburo baba mi, wọn si ba wa da si i, wọn pari ọrọ yẹn, oun naa si ṣeleri pe oun o ni i ṣiwọ soke lu mi mọ.

“Lẹyin naa lo rinrin-ajo lọ siluu eebo, o loun o ni i lo ju ọdun kan lọ, ṣugbọn ko ṣe bẹẹ, nigba ta a jọ sọrọ lori foonu, a tahun sira wa, lawọn mọlẹbi ẹ ba n pe mi niyawo buruku. Igba to ya, ko fi owo ounjẹ ṣọwọ si mi mọ, worobo pẹẹpẹẹpẹẹ ni mo n ta, emi ni mo mọ bi mo ṣe n gbọ bukaata lori awọn ọmọ wa, ko ba mi da si i mọ, gbogbo arọwa ti mo pa fun un lo ja si pabo.

“Nigba kan ti mo pe aago ẹ, obinrin lo gbe e lọhun-un, ẹni naa si sọ fun mi pe mi o tun le foju kan ọkọ mi mọ, o ni ki n tete maa ba temi lọ, o bu mi, o sọ oriṣiiriṣii ọrọ kobakungbe si mi.

“Ọdun 2022 yii to wale kẹyin, ti mo bi i leere bọrọ ṣe jẹ, o ni alaaanu oun lobinrin naa, ọwọ ẹ loun ti maa n ya owo toun fi n ranṣẹ si wa. Gbogbo igba ti ara mama mi o ya, titi ti wọn fi dakẹ, ọkọ mi o bikita, ko fowo ranṣẹ, igba to tun wale, ko tiẹ sọrọ nipa ẹ rara. Latigba to si ti pada, owo taṣẹrẹ kan bayii lo fi ṣọwọ, nigba ti mo si sọrọ nipa ẹ, o ni ki n maa dupẹ pe oun tiẹ fi nnkan kan ranṣẹ, tori oun o ni i fi nnkan kan ṣọwọ mọ to ba ya.

“Nigba kan ti mo ri i pe ko bikita fun mi, ti ara mi si n beere fun ibalopọ, mo yan ale, ẹẹkan ṣoṣo naa si ni. Ṣugbọn nigba tawọn mọlẹbi ẹ mọ si i, niṣe ni wọn fariga, wọn ni mo ti jẹ eewọ, mo gbọdọ ṣetutu ẹ, etutu naa si ni pe mo gbọdọ jo nihooho yika abule wọn, mo si gbọdọ san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira (N100,000) owo etutu, wọn ni igba yẹn ni mo too le maa lọ.

“Mo ba ọkọ mi sọrọ nipa ẹ, mo bi i lere boya o ṣi maa fẹ mi pada, o loun o fẹ mi mọ, ki n maa lọ.”

Bo tilẹ jẹ pe ọkọ Sandra ko si ni kootu naa, ẹgbọn rẹ, Cobina Iyenanye, to ṣoju fun un, fesi si ọrọ ti obinrin naa sọ, o gboriyin fun iyawo naa, o ni obinrin daadaa ni, o nifarada ati amumọra gidi, o si n tọju awọn ọmọ.

Cobina ni idi toun fi wa si kootu naa ni lati rọ ile-ẹjọ lati tu wọn kan nirọwọ-irọsẹ lai si ija, ki wọn si fun obinrin naa ni ẹtọ rẹ, ati awọn dukia to tọ si i nitori awọn ọmọ ati iwa rere rẹ.

Lẹyin atotonu wọn, Aarẹ ile-ẹjọ naa, Onidaajọ Adeniyi Kọledoye, sun igbejọ to kan si ọjọ keji, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, o nigba naa loun maa dajọ.

Leave a Reply