Awọn ọmọlẹyin Kristi darapọ mọ awọn Musulumi lati ro ilẹ Yidi

Monisọla Saka

Awọn ọdọ kan atawọn agbalagba ti wọn jẹ ọmọlẹyin Jesu nijọba ibilẹ Kachia, nipinlẹ Kaduna, ni wọn kun awọn Musulumi lọwọ lati roko aaye ti wọn yoo ti kirun Yidi ileya.

Ọkan lara awọn KrisItẹni to wa nibẹ, Ọgbẹni Daniel Bitrus, to ba akọroyin Daily Trust sọrọ sọ pe awọn ṣe eleyii lati mu ki ifẹ ati igbọra-ẹni-ye tubọ fẹsẹ mulẹ si i laarin awọn ẹlẹsin mejeeji lagbegbe naa.

O ni, “A wa sibi lati ran awọn ọmọ iya wa lọwọ fun riro awọn igbo, ati lati palẹmọ awọn idọti to wa layiika ibẹ lojuna ati mu ki alaafia ati iṣọkan jọba nilẹ wa”.

Iṣẹ yii ti wọn ṣe fun ọjọ meji, (ọjọ Abamẹta Satide ati ọjọ Aiku, Sannde) mu ki awọn Krisitẹni ati Musulumi raaye sọrọ daadaa, wọn bọ ara wọn lọwọ, bẹẹ ni wọn tun jiroro lori awọn ọna ti wọn le gba fi mu ki ifẹ ati iṣọkan gbooro laarin awọn ẹlẹsin mejeeji.

Wọn ni ero awọn ni pe awọn yoo maa ṣe eyi lọdọọdun lati le mu ki ifarada ati ifẹ jọba laarin awọn.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Akọwe ijọ, Jama’atu Nasril Islam(JNI), ẹka ti ijọba ibilẹ Kachia, Mallam Ibrahim Tasiu, fi idunnu rẹ han lori bi awọn ọmọlẹyin Kristi ṣe tu yaaya jade lati ran wọn lọwọ.

O fi kun un pe, koda, awọn eeyan naa ti de Yidi ṣaaju awọn Musulumi, nitori ati ba wọn palẹmọ fun ibi tawọn yoo ti kirun.

Inu ẹ dun, o si gboriyin fun wọn, paapaa ju lọ bo ṣe jẹ akọkọ iru ẹ ninu itan apa guusu ipinlẹ Kaduna nibi ti wọn ki i ti i yee ja ija ẹsin.

 

Leave a Reply