Ẹgbẹrun kọọkan Naira lalaisan yoo maa san fun ina ẹlẹntiriiki nileewosan UCH bayii

Ọlawale Ajao, Ibadan

Yatọ si owo ti ileewosan ọhun n gba lọwọ awọn alaisan, ẹgbẹrun kọọkan Naira (₦1,000) ni alaisan to ba lọọ gba itọju ni UCH, iyẹn ileewosan ijọba apapọ n’Ibadan, yoo maa san lojoojumọ bayii fun ina ilẹntiriiki nikan.

Ayipada tuntun yii ko yọ awọn alaisan ti wọn ba da duro sileewosan naa silẹ, ojoojumọ lawọn naa yoo maa san ẹgbẹrun kọọkan Naira gẹgẹ bii owo ina.

Ninu atẹjade kan ti awọn alaṣẹ ọsibitu yii fi sita gẹgẹ bii ikede laarin awọn oṣiṣẹ atawọn onibaara wọn lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni wọn ti kede igbesẹ tuntun naa.

Alakooso UCH, Ọgbẹni Wọle Oyeyẹmi, lo fọwọ si atẹjade naa lorukọ alaga igbimọ agba ati oludari agba pata lọsibitu naa.

Gẹgẹ bi wọn ṣe kọ ọ sinu ikede ọhun, wọn ni “ọwọngogo epo rọbi, eyi to mu ki epo diisu ta a maa n lo lati tan ẹrọ amunawa lojoojumọ gbowo lori gọbọi, lo fa sababi igbesẹ ta a gbe yii.

“Gẹgẹ bii ileewosan, paapa, ileewosan nla bii UCH yii, o pọn dandan fun wa lati maa lo ina nigba gbogbo, paapaa pẹlu bo ṣe jẹ pe ina lawọn irin-iṣẹ kan ta a fi n tọju awọn alaisan n lo.

“Ba a ṣe wa n tan ẹrọ amunawa lasiko ti epo diisu ti gbowo leri yii, bukaata epo rira lojoojumọ pẹlu owo gọbọi yii ti wọ igbimọ alaṣẹ ileewosan yii lọrun, a fẹ ki ẹyin onibaara wa naa maa ran wa lọwọ, ka jọ maa ṣe e.

“A rọ ẹyin onibaara wa lati fọwọsowọpọ pẹlu wa lori igbesẹ yii.”

Loju-ẹsẹ l’ALAROYE gbọ pe wọn ti n mu ilana tuntun yii lo, nitori lọgan ni wọn ti fi ikede naa ranṣẹ si gbogbo ibi ti awọn onibaara ileewosan naa maa n sanwo si.

Leave a Reply