Ẹṣọ Amọtẹkun Ondo ti sọrọ: Eyi lohun ta a mọ nipa akẹkọọ poli to ku l’Ọwọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Alakooso ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ti ṣalaye bi ọrọ ṣe jẹ lori ẹsun yiyin ibọn pa ọkan ninu awọn akẹkọọ Poli Ọwọ, eyi ti wọn fi kan awọn oṣiṣẹ abẹ rẹ nijọba ibilẹ Ọwọ.

Ọgọọrọ awọn akẹkọọ Poli Rufus Giwa, to wa niluu Ọwọ, ni wọn jade lati fẹhonu han ta ko iku ọkan ninu wọn, Fọlarera Ademọla, ẹni ti wọn lawọn Amọtẹkun ṣeesi yinbọn pa niwaju ile baba rẹ l’Ọwọ.

Oju ọna marosẹ to gba iwaju ileewe poli ọhun kọja lawọn akẹkọọ naa ti kọkọ bẹrẹ ifẹhonu han laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ki wọn too lọọ pari rẹ si ọfiisi gomina to wa ni Alagbaka, l’Akurẹ.

Lara ohun tawọn akẹkọọ ọhun lawọn n beere fun ni pe alakooso ẹṣọ Amọtẹkun gbọdọ fa oṣiṣẹ wọn to yinbọn pa ọkan ninu wọn le awọn ọlọpaa lọwọ fun iwadii to ye kooro.

Bakan naa ni wọn fi dandan le e fun ijọba pe wọn gbọdọ sanwo gba-ma-binu fawọn ẹbi oloogbe ti wọn da ẹmi rẹ legbodo.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi ṣọwọ si ALAROYE lati olu ileeṣẹ ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to pari yii ni Adelẹyẹ ti fidi rẹ mulẹ pe loootọ ni ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ajọ naa ṣeeṣi yinbọn pa akẹkọọ kan lasiko ti awọn n doju ija kọ ikọ awọn adigunjale kan niluu Ọwọ.

O ni iwadii tawọn ṣe fidi rẹ mulẹ pe awọn ọdaran kan wa niluu ọhun ti wọn ko niṣẹ meji ju ki wọn maa ṣe akọlu si awọn ọlọkada pẹlu ibọn atawọn nnkan ija oloro mi-in, ti wọn yoo si tun fipa ja ọkada wọn gba lọ.

Ọkan ninu awọn janduku ọhun lo ni awọn kofiri lọjọ kan, ti awọn si le titi to fi sa wọ ile kan nibi ti wọn ti ba awọn ẹgbẹ rẹ mẹẹẹdogun mi-in, ti meje ninu wọn si wa nihooho ọmọluabi.

O ni ṣe ni eefin igbo ti wọn n mu lọwọ gba gbogbo inu ile ọhun kan, ti awọn si tun ṣawari ọkada mẹrin ti wọn ko pamọ si ọkan ninu awọn yara to wa ninu ile naa.

O ni awọn ẹṣọ Amọtẹkun kọkọ ṣafihan ara wọn fun awọn gende ọhun nigba ti wọn kọkọ wọle, ṣugbọn dipo ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo naa, ṣe ni wọn mura ija, ti wọn si n gbiyanju lati ja ibọn gba lọwọ awọn Amọtẹkun.

O ni ori eyi ni wọn wa ti ibọn ti wọn n lọ mọ ara wọn lọwọ naa fi yìn lojiji, to si ṣeeṣi ba ọkan ninu awọn janduku ọhun ati oṣiṣẹ Amọtẹkun kan.

Adelẹyẹ ni awọn pada kapa awọn afurasi mẹẹẹdogun naa, awọn si fi pampẹ ofin gbe gbogbo wọn laimọ boya akẹkọọ wa lara wọn tabi bẹẹ kọ.

O ni lọjọ naa gan-an, iyẹn ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 ti iṣẹlẹ yii waye, ni ẹnikan to pe ara rẹ ni ẹbi afurasi to fara gbọta ọhun ti yọju lati gba beeli rẹ ko le tete lọọ gba itọju to yẹ.

Ẹni ọhun ṣeleri pe oun yoo mu ọkunrin naa pada wa laipẹ, ki awọn le tẹsiwaju ninu iwadii ti awọn n ṣe lọwọ lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Ọga ẹṣọ Amọtẹkun ọhun ni kayeefi patapata lo jẹ foun lati gbọ iroyin iku afurasi naa l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lẹyin bii ọjọ mọkanla ti wọn ti mu un kuro lọdọ awọn.

Adelẹyẹ ba awọn ẹbi oloogbe kẹdun lori iṣẹlẹ naa, bẹẹ lo si fi n da awọn araalu loju pe ẹkunrẹrẹ iwadii ti bẹrẹ lati ridii okodoro ohun to ṣokunfa iku akẹkọọ ọhun.

 

Leave a Reply