Eid IL Kabir: Oluwo rọ gbogbo ọmọ Naijiria lati gba ifẹ laaye, ki wọn si jẹ olotitọ

Florence Babaṣọla, Ọṣogbo

Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti ke si gbogbo awọn eeyan orileede Naijiria lati maa fi ifẹ han ninu iwa ati iṣe wọn.

Nibi irun ọdun Ileya to waye ni Yidi Ọba, lagbegbe Testing Ground, niluu Iwo, ni kabiesi ti sọ pe oore-ọfẹ nla ni ẹnikọọkan ni lati ṣe ọdun yii.

O ni iwa ati iṣe ẹnikọọkan gẹgẹ bii olugbe Naijiria ni yoo sọ bi orileede yii yoo ṣe ri, o rọ wọn lati mọ riri Ọlọrun, ki wọn si maa ṣe ifẹ rẹ.

Ọba Akanbi fi kun ọrọ rẹ pe ojiṣẹ Ọlọrun tẹle gbogbo ilana Ọlọrun lai ṣiyemeji, idi si niyẹn ti gbogbo eeyan fi n ṣapọnle rẹ latigba naa titi di asiko yii, o si sọ aginju di ibi ogo ti gbogbo eeyan n fẹ lati lọ.

O ni, “Ẹ jẹ ka polongo ifẹ, ka fa ọmọnikeji wa mọra, ka si fọwọsowọpọ fun imuṣẹ awọn afojusun wa. O ṣee ṣe ka ni orileede to duroore ti a ba ni ifẹ rẹ lọkan.

“Ẹ yago fun iwa jagidijagan. Ẹ ma ṣe faaye gba awọn oloṣelu lati lo yin, ẹyin funra yin ni ọjọ-iwaju rere, ẹ daabo bo o”.

Ni ti idibo gomina ọsẹ to n bọ nipinlẹ Ọṣun, Oluwoo rọ awọn araalu lati tu yaaya lọọ dibo, ki wọn ma si ṣe faaye silẹ fun wahala rara.

Leave a Reply