Ọlawale Ajao, Ibadan
Awọn agba bọ, wọn ni onlaja ni i fara gbọgbẹ. Ṣugbọn ọrọ buru ju bẹẹ lọ fun ọkunrin oniṣowo kan, Mufutau Sanni, ẹni ti wọn lu ṣe leṣe nibi to ti n laja, ti ifarapa to ni lasiko naa si pada ja siku oro fun un.
Ni nnkan bii aago kan ọsan ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keje, ọdun 2022 yii, nija bẹ silẹ laarin Yoruba kan pẹlu ọmọkunrin Hausa kan to n ta worobo lopoona ti wọn n pe ni Abiọla Way, nitosi ileepo Mobil, Ring Road, n’Ibadan.
Sanni, ẹni to jẹ alamoojuto tẹtẹ ti wọn n pe ni Baba Ijẹbu laduugbo naa, ko fẹ ki awọn onija yii gbẹmi ara wọn, ṣugbọn ẹmi oun paapaa ni wọn pada gba nibi to ti n la wọn nija.
Ọgbẹni Rẹmi Abimbọla to n ta iweeroyin tiṣẹlẹ ọhun ṣoju ẹ ṣalaye pe ọkan ninu awọn Hausa to n taja nibudokọ Mobil nija ṣẹlẹ laarin oun ati onibaara rẹ kan to jẹ Yoruba.
Ọna ti Sanni gba laja ọhun ko tẹ awọn Hausa to n gun ọkada nibẹ lọrun, ṣe Hausa lo pọ ju ninu awọn ọlọkada ibudokọ naa, n ni wọn ba ya bo o, wọn si lu u lalubolẹ bii ko ku mọ wọn lọwọ.
Lọgan ni wọn gbe ọkunrin onitẹtẹ naa lọ sileewosan, ṣugbọn nigba ti awọn dokita yoo fi ta mọra lati tọju ẹ, akukọ ti kọ lẹyin ọmọkunrin.
Awọn ọlọpaa pẹlu ikọ eleto aabo Amọtẹkun ti gbakoso gbogbo agbegbe naa lati dena ija tabi wahala to tun ṣee ṣe ko ṣẹlẹ lẹyin iṣẹlẹ yii.