Lati le gba kaadi idibo, ijọba Ogun kede ọjọ Iṣẹgun bii isinmi lẹnu iṣẹ

Gbenga Amos, Ogun 

Agan lọrọ eto idibo gbogbogboo to n bọ lọna dẹdẹ lọdun 2023, afi ki gbogbo araalu jọ gbe e, eyi lo mu ki Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, kede ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keje yii, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lenu isẹ jake-jado ipinlẹ naa, kawọn araalu le lọọ forukọ silẹ lati gba kaadi idibo alalopẹ wọn, iyẹn Permanent Voters’ Card (PVC), tabi kawọn to ti forukọsilẹ le lọọ gba kaadi wọn.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin gomina naa, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin, fi lede lọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii, o ni Dapọ Abiọdun faṣẹ si isinmi lẹnu iṣẹ lọjọ Tusidee ọhun, tori ko sẹni to gbọdọ ko iyan gbigba kaadi idibo PVC kere lasiko eto idibo to n bọ. O ni o ṣe pataki ki gbogbo ẹni to tọjọ ori rẹ ti to lati gba a ni in lọwọ, gẹgẹ bii ẹtọ ati agbara wọn, tori eyi ni ko ni i jẹ kẹnikẹni fi ẹtọ wọn lati yan adari rere sipo du wọn.

Atẹjade naa tun ṣalaye pe isinmi ọlọjọ kan naa yoo fun awọn eeyan ti kaadi PVC wọn ti sọnu, bajẹ, tabi ti wọn ti ṣipo pada lati ibi kan si ibomi-in, ati awọn ti wọn fẹẹ ṣatunṣe si akọsilẹ wọn lọdọ ajọ eleto idibo, Independent National Electoral Commission (INEC) lati ṣe bẹẹ, ki anfaani lati dibo ma baa fo wọn ru.

Gomina tun ran awọn araalu leti pe ajọ INEC ti gbe gbedeke ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje, yii kalẹ, lati fopin si gbogbo eto iforukọsilẹ ati gbigba kaadi naa.

O waa rọ awọn araalu lati gbe igbesẹ, ki kaluku lọ si wọọdu ati ẹkun idibo rẹ lati lọọ forukọ silẹ, ki wọn fọwọ si fọọmu wọn bo ṣe yẹ, ki wọn si tẹle awọn itọni ati ilana ajọ INEC.

O ni ireti wa pe didun lọsan yoo so lasiko eto idibo ọdun 2023 to wọle de tan yii.

Leave a Reply