Ibrahim Alagunmu
Onisowo pataki kan, Biọla Osundiyan, ni awọn agbebọn ti yinbọn pa nibi to ti n ṣe faaji lagbegbe gbọngan Aṣa, (Art and Culture), to wa lagbegbe Geri Alimi, niluu Ilọrin. Wọn ni o ṣẹṣẹ gba ipe arabinrin kan tan ni agbegbe to wa ni awọn agbebọn naa de, ti wọn si yinbọn pa a.
ALAROYE gbọ pe meji ni awọn agbebọn ọhun, ti wọn si fi ọkada dọdẹ rẹ de ibi ti wọn pa a si, wọn fi i lẹ sinu agbara ẹjẹ lẹyin ti wọn pa a tan, wọn si sa lọ.
A gbọ pe oniṣowo pataki ni Biọla, ilu Eko lo n gbe, o kan waa lo akoko diẹ pẹlu awọn mọlẹbi rẹ n’llọrin ni ki wọn too ṣeku pa a.
Aburo oloogbe to ba oniroyin wa sọrọ, Sẹgun, sọ pe inu ibanujẹ ni gbogbo mọlẹbi wa bayii lori iṣẹlẹ to gbomi loju ẹni ọhun. O rọ awọn ẹṣọ alaabo lati wa awọn olubi ẹda naa jade, ki wọn si foju wina ofin.
Alukoro ileesẹ ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, ni awọn ti gbọ si iṣẹlẹ naa, ṣugbọn oun ko le sọ bọya awọn ọmọ ẹgbẹ kunkun lo pa a tabi awọn onisowo ẹlẹgbẹ rẹ, ṣugbọn awọn ti n dọdẹ awọn ọdaran to pa a.