Iha aibikita ti Aarẹ Buhari kọ si awọn ipenija orileede yii lo n ṣakoba fun wa – Gani Adams

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alakooso apapọ fun ẹgbẹ Oodua Peoples Congress (OPC), Iba Gani Adams, ti ke si ijọba apapọ orileede yii lati wa ojutuu si ọrọ eto aabo to ti polukumuṣu ati ọrọ-aje wa to ti dẹnukọlẹ.

Aarẹ Ọna Kakanfo ni pẹlu ọwọ ti awọn adari fi mu ọrọ awọn ipenija to n koju Naijiria lọwọlọwọ, yoo ṣoro lati bori wọn lasiko.

Nibi eto ti Olokun Foundation sạgbekalẹ rẹ niluu Oṣogbo lara ayẹyẹ ọdun Ọṣun Oṣogbo ti ọdun yii, ni Iba Gani Adams ti woye pe iwa ko kan mi ti Aarẹ Mohammed Buhari n hu bayii ko le jẹ ki ọna abayọ tete wa lori ipenija eto-aabo ati ti ọrọ-aje ti orileede yii n dojukọ lọwọlọwọ.

O ni, “Yoo ṣoro lati yanju wahala eto ọrọ-aje to ti dẹnukọlẹ bayii lorileede Naijiria pẹlu ọna ti awọn adari n gba. Ko si ẹri idaniloju pe wahala ọrọ-aje yii le ju ọdun to n bọ lọ, ayafi tijọba ba tete ṣe atunto to yẹ.”

Lara awọn ọna abayọ ti Aarẹ Ọnakakanfo la silẹ kuro ninu laalaa eto ọrọ-aje yii ni kijọba apapọ mu ayipada ba iṣọwọṣiṣẹ ni ẹka naa, eleyii yoo tun ran eto aabo lọwọ.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ijọba apapọ gbọdọ mu atunto ba ẹka aabo ati eto ọrọ-aje lati le fopin si bi owo Naira ṣe di yẹyẹ lọja agbaye bayii.

“Ijọba apapọ gbọdọ di gbogbo alafo ti owo n gba jade ninu iṣejọba, ki wọn si tẹra mọ ọrọ okoowo ti yoo mu ki nnkan pada bọ sipo lawujọ.

“Bakan naa, a le wa ojutuu si ọrọ eto ọrọ-aje yii nipa fifaaye gba awọn oniṣẹ-ọwọ lati gbẹrẹgẹjigẹ lorileede yii.”

Aarẹ Adams lo anfaani naa lati ke si gbogbo iran Yoruba lati fi ọwọ to dara mu ọrọ aṣa ati iṣe, ki aṣa Yoruba ma baa lọ soko iparun.

Leave a Reply