Inu ori ẹja gbigbẹ ni ọkunrin yii tọju oogun oloro si tọwọ NDLEA fi ba a

Monisọla Saka

Ajọ to n gbogun ti ilokulo oogun ati ṣiṣe owo oogun oloro nilẹ yii, NDLEA, ti ri idi oogun oloro to le ni irinwo (442) ti wọn ko sinu ori ẹja gbigbẹ. Lẹyin ti wọn ko o sibẹ tan ni wọn di i sinu paali, ṣugbọn aṣiri wọn pada tu, awọn agbofinro mu wọn, wọn si gba ẹru ofin yii silẹ lọwọ wọn ni papakọ ofurufu Eko, ki wọn too gbe e kọja si Dubai.

Ẹka ileeṣẹ to n ba wọn ko ẹru ranṣẹ ti wọn n pe ni SAHCO, to wa  ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed, Ikẹja, nipinlẹ Eko, ni wọn fẹẹ gba gbe ẹru ọhun lọ si oke okun ki ọwọ too tẹ wọn.

Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ajọ NDLEA, Fẹmi Babafẹmi, fi lede lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lo ti ṣalaye pe ọkunrin kan to n jẹ Adekunle Oluwapẹlumi Paul, ẹni ọdun mejilelọgbọn, lati ijọba ibilẹ Yagba, nipinlẹ Kogi, lo fi ẹru ran ileeṣẹ SAHCO. Ninu ẹru naa lo ko oogun oloro ti iwọn rẹ din diẹ ni kilo mejila si, to si gbe e wa si papakọ ofurufu lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ.

O ni lọgan ti wọn ri i pe paali mejeeje to gbe wa pe oun fẹẹ fi ranṣẹ si oke okun kun fun oogun oloro ti wọn di si ọra yinrinyinrin (foil paper) ki wọn too tọju ẹ pamọ sinu obitibiti ori ẹja gbigbẹ ni wọn fi panpẹ ofin gbe afurasi ọhun.

Lọjọ keji, to jẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹjọ, ni wọn tun gba afurasi mi-in mu pẹlu igbo to din diẹ ni kilo kan aabọ (1.45kg) to tọju pamọ sinu ede ati ẹgusi lilọ, to si di i mọ awọn ounjẹ mi-in pẹlu erongba lati gbe e sọda lọ si ilu Dubai. Ileeṣẹ SAHCO to wa ninu papakọ ofurufu yii kan naa ni Ajiṣefini Lateef, ẹni ọdun mọkandinlogoji (39) to jẹ ọmọ bibi ijọba ibilẹ Iwọ Oorun Abẹokuta ti fẹẹ fi ẹru ofin to di sinu ẹgusi ati ede lilọ ọhun ranṣẹ kọwọ ajọ NDLEA too tẹ ẹ.

” Alaga ati adari ajọ NDLEA, Mohammed Buba Marwa, gboriyin fun awọn oṣiṣẹ wọn ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed ati Tincan, l’Ekoo, Kaduna ati Abia fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati le gba awọn oogun oloro ati bi wọn ṣe ri awọn ọdaran naa gba mu. O ke si awọn eeyan ẹ kaakiri orilẹ-ede yii lati ji giri, ki wọn le maa ja gbogbo ete ati ọgbọn ti awọn ọdaran naa le maa ta, ki adinku si ba iwa laabi yii lorilẹ-ede Naijiria.

Leave a Reply