Alaga ẹgbẹ PDP pariwo: Ẹ ma da wọn lohun, mi o fipo mi silẹ

Faith Adebọla

 Ariwo to kọkọ gbode kan lori ẹrọ ayelujara lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ yii, ni pe Alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Ọgbẹni Iyorchia Ayu, ti kọwe fipo silẹ, o ti gba lati kuro nipo naa lati gba alaafia laaye ninu ẹgbẹ wọn.

Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọsan ọjọ naa, niṣe ni iroyin mi-in tun jade, nibi ti Alaga naa ti n sọrọ niluu Ekiti, nigba ti wọn lọọ ki awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu SDP rẹpẹtẹ kan ti wọn ṣẹri pada sinu PDP kaabọ. Nibẹ ni Alaga naa ti sọ pe ko sootọ ninu ọrọ to n lọ pe oun ti kọwe fipo silẹ, o ni irọ ni, oun ko fi ipo Alaga silẹ, tori ọdun mẹrin ṣangiliti ni wọn dibo yan oun lati lo lori ipo naa, ko si si lerongba oun lati kuro nibẹ lasiko yii, tori oun ko ri idi fun iru ipinnu bẹẹ.

Lati fidi ipinnu rẹ yii mulẹ, ọrọ pataki kan ti Ayu gbe soju opo ayelujara tuita rẹ lọjọ Mọnde ni pe: “Mi o ti i kuro nipo Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP o, ọdun mẹrin ni iyansipo mi gẹgẹ bii ofin, ko si si lerongba mi lati kuro lasiko yii tabi lọjọ iwaju, ki ọdun naa too pe”.

Ṣaaju ni agba ẹgbẹ oṣelu naa to mọ bi ọrọ ṣe n lọ, to si ti figba kan jẹ ọmọ ẹgbẹ igbimọ alakooso ẹgbẹ naa, ṣugbọn ti ko fẹ kawọn oniroyin darukọ oun, lo taṣiiri ọrọ naa lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ yii, nibi ipade ipẹtu-saawọ kan to n lọ lọwọ laarin awọn agbaagba atawọn gomina ẹgbẹ naa niluu Abuja.

Ọkunrin naa fidi rẹ mulẹ pe Alaga ẹgbẹ wọn, Sẹnetọ Iyorchia Ayu, ti kọwe fipo naa silẹ ṣaaju apero akanṣe naa to waye, o ni lẹta rẹ ti wa lọwọ Alagba David Mark.

“Kin ni Ayu fẹẹ fi ṣeranwọ fun Atiku? O gbọdọ kọwe fipo silẹ to ba jẹ ẹni iyi loootọ. O ṣaa ti buwọ lu lẹta ifipo-silẹ rẹ, lẹta naa wa lọwọ David Mark, ẹ ni ki David Mark sọrọ jade, tori Ayu ti loun maa kọwe fipo silẹ to ba fi jẹ iha Ariwa ni ẹgbẹ PDP ti mu aarẹ.

Ọkunrin naa sọ pe awọn kan ni wọn ko fẹ ki Ayu lọ. Wike padanu ipo oludije fun aarẹ, ati ipo igbakeji aarẹ, o si ni ki alaga ẹgbẹ naa fipo silẹ. Bi Atiku ba fẹẹ ṣootọ, o yẹ ko jẹ ki Ayu maa lọ nirọwọ-irọsẹ, o le ba a wa ipo mi-in, tabi ipo to nikimi ninu ijọba rẹ to ba wọle, iyẹn lo le dun mọ Wike atawọn alatilẹyin rẹ ninu. Gbogbo wa la gbọdọ ṣiṣẹ ki ẹgbẹ le goke si i.”

Ọjọ Aje yii kan naa lawọn igbimọ ẹlẹni mẹrinla kan ti Atiku ati Wike gbe kalẹ lati yanju lọgbọ-lọgbọ to n lọ laarin awọn alatilẹyin Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, ati oludije funpo aarẹ wọn, Alaaji Abubakar Atiku, bẹrẹ ijokoo wọn, ti wọn fori kori l’Abuja, lati fori ikooko ṣọọdu, ṣugbọn lopin ijokoo ọhun, niṣe ni wọn ṣi so ijiroro wọn rọ na, wọn ni ki kaluku lọọ ronu lori ọna abayọ to daa ju lọ si lọgbọlọgbọ naa.

Ọkan lara ohun ti Wike ati awọn alatilẹyin si n beere ni pe ki ipindọgba wa, tori ipo oludije fun aarẹ ati alaga ẹgbẹ ko le wa lati agbegbe kan naa, iyẹn Oke-Ọya.

 

Leave a Reply