Nitori tiyẹn ni ko ma mu igbo mọ, Vincent binu du iya-iya rẹ bii eran l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Iya ẹni aadọrin ọdun kan ti pade iku ojiji lati ọwọ ọmọ-ọmọ rẹ, Vincent,  niluu Ondo, lọsẹ to kọja yii.

Iṣẹlẹ yii waye lagbegbe Labẹta, Orimọlade, Sabo, Ondo, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Vincent ni wọn lo f’ọbẹ dumbu iya agbalagba ọhun bii ẹran sinu palọ ile wọn lori ẹsun pe o fi aidunnu rẹ han si bo ṣe n mu igbo to n mu.

Ni ibamu pẹlu alaye ti ọmọkunrin kan to jẹ aburo Vincent, Pẹlumi, sọ, o ni oun ati ẹgbọn oun lawọn jọ n gbe pọ pẹlu mama ti wọn pa ọhun.

Ọmọkunrin yii ni bo tilẹ jẹ pe iya agba naa ko fi bẹẹ fẹran ko maa rojọ awọn ọmọ rẹ sita fawọn eeyan, ṣugbọn gbogbo igba loun ati ẹgbọn oun, iyẹn Vincent, maa n ja, to si maa n ba a wi lori ọrọ igbo mimu, eyi to ti di baraku fun un.

Pẹlumi ni iya agba lo ran oun niṣẹ lọsan-an ọjọ iṣẹlẹ naa pe ki oun lọọ ra igbin wa l’ọja, ki oun le fi ṣe ọbẹ ti oun fẹẹ ṣe, nitori pe ko sohun to wu oun lati fi ṣe ọbẹ ọhun ju igbin lọ.

O ni bi oun ti fẹẹ maa jade lọ loun pade ẹgbọn oun to n wọle bọ, to si ni oun fẹẹ lọ aṣọ oun. Pẹlumi ni bi oun ṣe gbe aayọọnu ilọṣọ fun un tan loun ni oun jade lọ ni toun.

Pẹlumi ni inu yara loun ba iya agba ati ẹgbọn oun nigba toun pada de lati ibi ti oun ti lọọ ra igbin, o ni b’oun ṣe n wọle ni mama tun ran oun niṣẹ lati lọọ wa igi idana ti wọn fẹẹ fi dana wa.

Bo ṣe wa igi idana tan to n pada wọle lo ni oun ba iya awọn nilẹ ninu agbara ẹjẹ nibi ti wọn du u lọrun si.

O ni ede aiyede kan ti kọkọ waye laarin Vincent ati iya agbalagba ọhun lọjọ iṣẹlẹ naa lori bi ọmọkunrin naa ṣe kọ jalẹ lati ro oko ti mama ni ko ro.

Ṣe ni Vincent ti wọn fẹsun kan naa ṣẹ kanlẹ lori ọrọ iku iya agbalagba ọhun, o ni kete ti aburo oun kuro nile loun naa ti jade lọ, igba toun yoo fi pada d’ele lo ni oun ba mama ninu agbara ẹjẹ.

O ni oun gan-an loun kọkọ pariwo sita lati fi iṣẹlẹ naa to awọn araadugbo leti.

Awọn ọlọpaa tesan Fagun, niluu Ondo, ni wọn kọkọ fi iṣẹlẹ ọhun to leti, ohun ta a gbọ ni pe awọn agbofinro ti n gbe igbesẹ lati fi tẹgbọn taburo naa ṣọwọ si olu ileeṣẹ wọn to wa l’Akurẹ fun ifọrọwanilẹnuwo kikun.

 

 

Leave a Reply