Awọn alatilẹyin oludije funpo aarẹ kan fiku halẹ mọ mi – Mista Macaroni

Faith Adebọla, Eko

 Gbajugbaju adẹrin-in poṣonu nni, Debọ Adedayọ, ti ọpọ eeyan mọ si Misita Macaroni ti kegbajare pe awọn eeyan kan ti n dunkooko mọ oun, wọn n fiku halẹ mọ oun ati awọn mọlẹbi oun, wọn loun ko ṣatilẹyin fun oludije funpo aarẹ tawọn n tẹle.

Lori ikanni ayelujara tuita (twitter) rẹ ni Mista Macaroni gbe ọrọ kan si lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ yii, lati ṣalaye bọrọ naa ṣe jẹ, o ni:

“Mo lọọ ki mama mi lọsẹ meji sẹyin, mo si n fawọn eeyan kan lowo gẹgẹ bi mo ṣe maa n ṣe nigbakuugba ti mo ba lọ sọdọ wọn. Obinrin kan rin sun mọ mi, o beere lọwọ mi pe ki lo de ti mo kọyin si oludije kan bayii bayii, mo ni emi o kọyin sẹnikẹni, temi ṣaa ni ki orileede wa ti daa.

Ohun to si le mu korileede wa dara ni ki gbogbo wa dibo yan awọn adari rere sipo. Ohun to maa sọ tẹle e ni pe kemi yaa ṣọra mi gidigidi o, tori awọn mọ ibi tawọn eeyan mi n gbe. Mo bi i lere pe ṣe o fẹẹ maa dunkooko mọ mi ni, lo ba bẹrẹ si i sọrọkọrọ lẹnu. Ẹgbọn mi ati maneja mi wa lọdọ mi, mo si ya fidio gbogbo ọrọ yẹn pamọ.

Mi o le ka oriṣiiriṣii idunkooko mọ ni, ihalẹ ti wọn ti ṣe si mi, latọdọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu tabi awọn ọmọlẹyin oludije ti mo n sọrọ ẹ yii, tori wọn gbagbọ pe mi o ṣe tiwọn, mi o si tẹle ẹni tawọn fẹ. Wọn aa halẹ mọ mi lori ẹrọ ayelujara, wọn aa bu eebu, wọn aa paroko loriṣiiriṣii, tabi ki wọn maa gbekeyide lori ẹya ti wọn jẹ.

Irọ ati ẹtan ti pọ ju, niṣe lo si n buru si i lojoojumọ. Ṣugbọn bi a gun ata lodo, bi a lọ ata lori ọlọ, iwa ata ko ni i pada, ọrọ ati ero mi ko le yipada o. Iya to n jẹ wa ni Naijiria yii to gẹẹ, o ti to gẹẹ. Ẹ wo yika, ẹ wo ipenija ati iṣoro ti gbogbo wa dojukọ, ki lo de!

Ko si olugbala kan nibi kan. Ṣugbọn ta a ba fẹ ki orileede yii dara si i lọdun 2023, afi ka ri i pe a yan ẹni to kunju oṣuwọn ju lọ sipo olori ilu wa yii. A gbọdọ ṣayewo awọn oludije wọnyi lọkọọkan, ka wo ipilẹ wọn, akọsilẹ irinajo aye wọn, ironu ati erongba wọn, okun ati agbara wọn, ka si pinnu boya wọn le ṣe e tabi ẹmi wọn o gbe e, iyẹn lori ipo ti wọn lawọn fẹẹ bọ si.

Ẹ jẹ ka wa fin-in idi koko kaluku wọn, ka le mọ oludije to yẹ ka dibo fun. Ọrọ temi ko ju bẹẹ lọ, mo danu duro na o.”

Bo tilẹ jẹ pe Mista Macaroni ko darukọ oludije kan pato, sibẹ ọpọ eeyan to ka ọrọ to kọ yii ti n fura ẹni to ṣee ṣe ko jẹ.

Ọpọ awọn ọrẹ alawada naa ni wọn si n ṣadura fun un pe ko ma ṣe mikan, wọn ni bawọn oloṣelu ṣe maa n halẹ ma’wọn ti ko ba ṣe tiwọn niyẹn, pe ko sohun ti yoo ṣe e.

Leave a Reply