Lẹyin ti Ọlaniyi tẹwọn de lo tun lọọ fọ ṣọọbu l’Ẹdẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ ọmọkunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Akintunde Ọlaniyi Joy, lori ẹsun ole-jija.

Gẹgẹ bi Alukoro funleeṣẹ ọlọpaa, Yẹmisi Ọpalọla, ṣe ṣalaye, o ni Ọlaniyi to jẹ akẹkọọ poli kan nipinlẹ Ọṣun, ti kọkọ ṣẹwọn ọdun kan lọdun 2018 lọgba ẹwọn ilu Ileefẹ, lẹyin to de lo tun lọọ jale.

Ọpalọla sọ siwaju pe ninu oṣu Keje, ọdun yii, ni ọkunrin kan to n ta foonu niluu Ẹdẹ, Akinkunmi Abass, lọọ fi to awọn ọlọpaa leti pe lati oṣu Kẹta, ọdun yii, lawọn adigunjale ti n fọ ṣọọbu oun, ti wọn si n ko foonu olowo iyebiye.

O ni lasiko ti awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii ni ọwọ tẹ Ọlaniyi nipasẹ foonu kan to ji ni ṣọobu Akinkunmi, to si bẹrẹ si i ka boroboro nipa awọn iṣẹ ibi to ti ṣe sẹyin.

Ninu ijẹwọ rẹ lo ti sọ pe oun atawọn ẹgbẹ oun lọ si ṣọọbu Akinkunmi ninu oṣu Kẹta, ọdun yii, ti awọn si ji oniruuru foonu ti owo rẹ din diẹ ni miliọnu mẹrin Naira.

O ni lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, awọn tun lọ si ṣọọbu yẹn laago meji oru, nibi ti awọn ti de ọlọdẹ mọlẹ, ti awọn si ji foonu ti owo rẹ jẹ miliọnu lọna mọkandinlọgbọn Naira.

 

Fungba kẹta, Ọlaniyi sọ siwaju pe awọn tun pada lọ si ṣọọbu naa lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un ọdun yii, awọn si tun ji foonu ti owo rẹ to miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna igba Naira.

Ọlaniyi tun jẹwọ pe aimọye ṣọọbu lawọn tun ti fọ niluu Ẹdẹ, ti awọn si ji oniruuru nnkan bii aṣọ, bata atawọn nnkan eelo inu ile ati bẹẹ bẹẹ lọ nibẹ.

Ọpalọla ni awọn ti wọn fọ ṣọọbu ti n wa lati yẹ awọn nnkan ti wọn ba lọdọ Ọlaniyi wo, to si jẹ pe ṣe lo ji gbogbo ẹ.

O ni iṣẹ ti n lọ lati wa awọn ti wọn n ṣiṣẹ papọ pẹluafurasi ọdaran naa, laipẹ ni yoo si foju bale-ẹjọ.

 

Leave a Reply