Ajọ eleto idibo Ọṣun kede ọjọ ti idibo ijọba ibilẹ yoo waye

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ajọ to n ṣe kokaari eto idibo ijọba ibilẹ nipinlẹ Ọṣun, Osun State Independent Electoral Commission (OSIEC), ti kede pe ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni eto idibo ijọba ibilẹ yoo waye.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ laipẹ yii, Alaga ajọ naa, Ọtunba Ṣẹgun Ọladitan, ṣalaye pe oniruuru awọn ipenija to n da ajọ naa duro tẹlẹ lo ti kuro bayii.

O ni wahala ajakalẹ arun Korona fi ọpọlọpọ asiko ṣofo, nigba ti ifẹhonu han Endsars tun ṣe tiẹ. O ni oniruuru ẹjọ ni ajọ naa koju ni kootu, ko too di pe ọna la fun idibo naa bayii.

Ọladitan fi kun ọrọ rẹ pe idibo ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹwaa ọhun, yoo wa fun ipo alaga kansu ati awọn kanselọ ni gbogbo wọọdu gegẹ bo ṣe wa ninu alakalẹ abadofin kan ti ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun ṣẹṣẹ buwọ lu.

O ni ṣaaju ikede yii ni ajọ naa ti ṣepade pẹlu gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun ti wọn ni aṣoju nipinlẹ Ọṣun, to fi mọ ẹgbẹ oṣelu PDP, oun si ti ṣalaye fun wọn lẹkun-unrẹrẹ nipa idi ti idibo naa fi gbọdọ waye.

Ọladitan ke si ẹgbẹ oṣelu to ba ni ohun kan tabi omi-in lori ọrọ eto idibo naa ki wọn lọ sile-ẹjọ, dipo ki wọn maa sọrọ ihalẹ mọ awọn ọmọ ajọ naa lori ẹrọ ayelujara ati iwe iroyin.

Leave a Reply