Ibo Gomina Ogun 2023: Awọn ọba Yewa ni Dapọ Abiọdun lawọn n ba lọ o

Gbenga Amọs, Ogun

Awọn ọba alaye lorigun mẹrẹẹrin ilẹ Yewa, ni ẹkun idibo apapọ Iwọ-Oorun ipinlẹ Ogun, ti buwọ lu erongba Gomina ipinlẹ naa, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, lati dupo gomina lasiko eto idibo gbogbogboo to maa waye lọdun 2023, wọn lawọn faṣẹ si i ko lo saa keji nipo naa.

Olori awọn ọba agbegbe naa, Olu ti Ilaro, Ọba Kẹhinde Olugbenle, lo sọrọ yii di mimọ lasiko ayẹyẹ ọjọọbi aadọrin ọdun oniṣowo pataki ọmọ bibi ipinlẹ Ogun nni, Alaaji Akeem Adigun, eyi to waye niluu Eko, lopin ọsẹ to kọja yii.

Nibi ayẹyẹ naa, ti ọpọ awọn eekan eekan oloṣelu ati oniṣowo, atawọn ọba alaye pesẹ si, titi kan Dapọ Abiọdun funra rẹ, ni Olugbenle ti ṣiṣọ loju eegun pe to ba jẹ eto idibo sipo gomina Ogun lọdun 2023 to n bọ yii, awọn ti pari iṣẹ lori ẹ, awọn o si lero mi-in ju pe Abiọdun lawọn n ba lọ atawọn ẹmẹwa awọn.

“Ni ajọ awọn lọbalọba ti Yewa, ko si ija tabi aawọ kan mọ lori ẹni ti yoo dupo gomina, ileegbimọ aṣoju-ṣofin ati ipo sẹnetọ, tori awa ti fẹnu ọrọ jona ni tiwa.

“A dupẹ lọwọ gomina fun ifẹ ti wọn ni sawọn eeyan agbegbe Yewa, a si fẹẹ fi da yin loju pe gbọn-in gbọin-in bii oke lawọn ọdọkunrin ati ọdọbinrin wa duro ti yin fun ti idibo to n bọ lọna.

“Gbogbo awọn ti wọn o ti i m’ọnu odo tawọn yoo da ọrunla si lori ọrọ yii lo ṣi maa ye nigbẹyin, o maa ka loju wọn nigba ti a ba fi ibo wa gbe e yin wọle pẹlu ibo rẹpẹtẹ,” gẹgẹ b’Ọba Ilaro ṣe wi.

O lawọn ti ri ọwọ iṣẹ rere Gomina Abiọdun lagbegbe awọn, ati kaakiri ipinlẹ naa, awọn si fẹ ko tẹsiwaju lati mu ilọsiwaju ba ipinlẹ Ogun.

Dapọ Abiọdun naa dupẹ lọwọ awọn ọba alaye naa fun atilẹyin wọn, o si ṣeleri lati jara mọṣẹ si i nipinlẹ Ogun.

Leave a Reply